DECEMBER 2, 2016
ÍTÁLÌ
Àwọn Aláṣẹ ní Ítálì Fàyè Gba “Gbọ̀ngàn Ìjọba” Nínú Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Torí Pé Ó Ń Ṣe Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Làǹfààní
ÌLÚ RÓÒMÙ—Torí pé àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n ìlú Bollate rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ran àwọn aráàlú lọ́wọ́, wọ́n fún àwọn Ẹlẹ́rìí ní yàrá ńlá kan nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sílùú Milan, pé kí wọ́n máa fi ibẹ̀ ṣe “Gbọ̀ngàn Ìjọba,” tàbí ibi tí wọ́n á ti máa jọ́sìn.
Dr. Massimo Parisi, tó jẹ́ ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, sọ pé torí àtimáa ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́ káyé wọn lè dáa ni wọ́n ṣe kọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, ó ní: “Ọ̀kan lára ohun tá a máa ń fẹ́ ṣe ni pé ká jẹ́ káwọn èèyàn pa dà nírètí pé ayé wọn ò bà jẹ́ kọjá àtúnṣe, oríṣiríṣi ọ̀nà la sì máa ń gbà ṣe èyí. A tún gbà pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run.” Ọdún mẹ́tàlá [13] sẹ́yìn báyìí ni àwọn aláṣẹ ti gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè kí wọ́n máa wá kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Dr. Parisi sọ ohun tó ti tẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà yọ, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa, ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n wa ti nípa rere lórí àwọn kan nínú wọn. . . . Torí náà, a wò ó pé ó dáa ká fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbì kan nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n wa, kí wọ́n lè máa kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n yìí níbẹ̀ káyé wọn lè dáa.” Láàárín oṣù mélòó kan sẹ́yìn, ẹ̀ẹ̀mejì la rí i pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ló wá síbi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.
Christian Di Blasio tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé: “Inú wa dùn pé àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n Bollate fún wa níbi tá a ti lè máa jọ́sìn nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kí wọ́n lè fìyẹn tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń ran àwọn aráàlú lọ́wọ́. À ń retí pé wọ́n á máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa, kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n lè máa jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a dìídì ṣe torí wọn kí wọ́n lè sún mọ́ Ọlọ́run.”
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000
Ítálì: Christian Di Blasio, 39-06-872941