Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 24, 2017
ÍTÁLÌ

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Ṣẹlẹ̀ ní Erékùṣù Kan Lórílẹ̀-Èdè Ítálì

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Ṣẹlẹ̀ ní Erékùṣù Kan Lórílẹ̀-Èdè Ítálì

Ní August 22, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára kan ṣẹlẹ̀ ní erékùṣù Ischia tó wà létíkun ìlú Naples, lórílẹ̀-èdè Ítálì. Ìmìtìtì ilẹ̀ náà ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé jẹ́, ó sì sọ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [2,600] èèyàn di aláìnílé. Ó lé ní ogójì [40] èèyàn tó fara pa, àwọn méjì ló sì kú.

A ò tíì gbọ́ pé ìkankan nínú àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [633] Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé ní erékùṣù náà ko jàǹbá tàbí fara gbọgbẹ́, àmọ́ ilé àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́sàn-án ló bà jẹ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè náà ti ń ran àwọn ará bíi tiwọn lọ́wọ́, ìyẹn àwọn tọ́rọ̀ yìí kàn, wọ́n sì ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wọ́n nínú.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Ítálì: Christian Di Blasio, +39-06-872941