Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 1, 2016
ÍTÁLÌ

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Àárín Gbùngbùn Orílẹ̀-èdè Ítálì

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Àárín Gbùngbùn Orílẹ̀-èdè Ítálì

Láàárọ̀ ọjọ́ Sunday, October 30, 2016, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára wáyé ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Ítálì, òun ni ìmìtìtì ilẹ̀ tó le jù tó tíì ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà látọdún 1980. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó kéré tán, ogún [20] èèyàn ló fara pa, ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ ni pé kò sẹ́ni tó kú.

Ìlú Norcia ni ìmìtìtì yìí ti rinlẹ̀ jù, ẹ̀ẹ̀kẹta tó sì máa ṣẹlẹ̀ ní ìlú yìí kan náà nìyí láàárín ọjọ́ mélòó kan. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Wednesday, October 26, 2016, ìmìtìtì ilẹ̀ kan wáyé níbẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn wákàtí méjì, òmíì tó le ju ìyẹn lọ tún ṣẹlẹ̀.

Tòsí ibi tí ìmìtìtì ilẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní August 24, tó sì pa àwọn èèyàn tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ni àwọn èyí tó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti ṣẹlẹ̀.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò kú, ìkankan nínú wọn ò sì fara pa yánnayànna, àmọ́ ó kéré tán, ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ni ilé wọn pa rẹ́ nígbà tí ilẹ̀ mì tìtì ní October 26, ilé ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí míì ló sì bà jẹ́. Àwọn alàgbà ti kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ kí wọ́n lè mọ ohun tí wọ́n nílò àti nǹkan wọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bà jẹ́, torí pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ò tíì bọ́ nínú ìṣòro tí ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé ní August fà. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni kò sun ilé wọn mọ́, bíi táwọn míì tí àjálù náà kàn, torí ẹ̀rù ń bà wọ́n pé nǹkan míì lè ti ṣe ilé àwọn kí àwọn má mọ̀, torí náà, wọ́n lọ ń sun inú mọ́tò àtàwọn ọkọ̀ tó nílé lẹ́yìn, àwọn kan sì ń sun inú Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti ń jọ́sìn.

Láti oríléeṣẹ́ wa ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò bá a ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá, wọ́n ń lo owó táwọn èèyàn fi ń ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Ítálì lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé mọ́kànléláàádọ́ta [251,000].

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Ítálì: Christian Di Blasio, 39-06-872941