MAY 23, 2018
ÍTÁLÌ
Àpérò Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Wáyé ní Yunifásítì Padua Láti Jíròrò Ìtẹ̀síwájú Tó Ti Bá Ọ̀rọ̀ Títọ́jú Aláìsàn Láìlo Ẹ̀jẹ̀
ÌLÚ RÓÒMÙ—Ní Friday, November 24, 2017, àwọn onímọ̀ ìṣègùn àtàwọn amòfin pàdé pọ̀ ní Yunifásítì Padua, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn yunifásítì tó tíì pẹ́ jù nílẹ̀ Ítálì. Wọ́n wá ṣe àpérò tí wọ́n pe àkòrí ẹ̀ ní “Àwọn Aláìsàn Tó Dàgbà Ò Fẹ́ Gbẹ̀jẹ̀: Kí Lọ̀nà Àbáyọ?—Ètò Títọ́jú Ẹ̀jẹ̀ ti Ọdún 2017.” Àwọn ẹgbẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lóríṣiríṣi tí wọ́n ju mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló ṣe onígbọ̀wọ́ àpérò náà, títí kan Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Ìlera ní Ítálì.
Ọ̀pọ̀ ló gbà pé fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára kò léwu, wọ́n sì gbà pé òun nìkan lọ̀nà àbáyọ fáwọn aláìsàn tí ọ̀rọ̀ ìtọ́jú wọn tàbí iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fẹ́ ṣe díjú. Àmọ́ púpọ̀ nínú àwọn tó sọ̀rọ̀ níbi àpérò náà ni kò fara mọ́ èrò yìí. Ọ̀kan lára àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó wá síbẹ̀ ni Dókítà Luca P. Weltert, tó máa ń ṣiṣẹ́ abẹ níbi ọkàn àti igbá àyà nílé ìwòsàn European Hospital nílùú Róòmù. Ó sọ pé: “A ti rí i báyìí pé fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára léwu, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé kò pọn dandan kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí aláìsàn lára.”
Ohun tó mú kí Dókítà Weltert àtàwọn dókítà míì tó wá síbi àpérò yìí parí èrò síbẹ̀ ni ohun tójú wọn ti rí pẹ̀lú àwọn aláìsàn tí wọ́n ń tọ́jú àtàwọn ẹ̀rí látinú ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ṣe tó jẹ́ kí wọ́n rí i pé iye àwọn tó ń kú lẹ́yìn tí wọ́n gba ẹ̀jẹ̀ ń pọ̀ sí i, wọ́n túbọ̀ ń ṣàìsàn, wọ́n ń pẹ́ nílé ìwòsàn, oríṣiríṣi àwọn nǹkan míì tó le gan-an tó sì ń ba ìlera jẹ́ ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó gba ẹ̀jẹ̀ sára. *
“A ti rí i báyìí pé fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára léwu, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé kò pọn dandan kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí aláìsàn lára.”—Dókítà Luca Weltert, oníṣẹ́ abẹ lórí ọkàn àti igbá àyà ní European Hospital nílùú Róòmù
Ẹ̀rí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rí yìí, pẹ̀lú bí iye owó tí wọ́n fi ń fa ẹ̀jẹ̀ síni lára ṣe pọ̀ tó ló mú kí Àjọ Ìlera Àgbáyé (ìyẹn WHO) ṣe ètò kan lọ́dún 2010 tó dá lórí ìdí tó fi yẹ kí àwọn onímọ̀ ìṣègùn máa ṣọ́ ẹ̀jẹ̀ aláìsàn lò. Wọ́n pe orúkọ ètò náà ní PBM, ètò yìí kan gbogbo apá ìmọ̀ ìṣègùn, ó sì kan gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìlera, dídá ààbò bo aláìsàn, ìtọ́jú tó dára sí i àti bí wọ́n á ṣe dín fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára kù. Àjọ WHO rọ gbogbo ìjọba orílẹ̀-èdè mẹ́tàléláàádọ́wàá (193) tó wà nínú Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n fara mọ́ àwọn àbá ètò PBM.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Stefania Vaglio, tó jẹ́ ọ̀gà àgbà ní ẹ̀ka ìfàjẹ̀sínilára nílé ìwòsàn Sant’Andrea University Hospital nílùú Róòmù ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ètò PBM tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yìí. Ó sọ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ẹlòmíì tí wọ́n gbà sílẹ̀ ni wọ́n máa ń lò láti tọ́jú aláìsàn, àmọ́ ní báyìí, “nǹkan ti yí pa dà pátápátá, ẹ̀jẹ̀ aláìsàn gangan là ń lò báyìí.” Ọ̀kan lára ìdí tí wọ́n fi ṣe ètò PBM ni “láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ aláìsàn náà jẹ àwọn dókítà lógún kí wọ́n lè dín ẹ̀jẹ̀ tó ń ṣòfò kù, . . . láti pọkàn pọ̀, kí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣọ́ ẹ̀jẹ̀ aláìsàn lò.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Vaglio tún jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà tọ́jú aláìsàn láìjẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ṣòfò “jẹ́ ọ̀nà ìtọ́jú tó mọ́yán lórí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”
Dókítà Tommaso Campagnaro, tó jẹ́ oníṣẹ́ abẹ nílé ìwòsàn Verona University Hospital jẹ́rìí sí i pé àǹfààní wà nínú ìtọ́jú tí kò la fífa ẹ̀jẹ̀ síni aláìsàn lára lọ. Lẹ́yìn tó sọ àwọn ìwádìí kan tó ti ń ṣe bọ̀ láti nǹkan bí ọdún 1997, nípa àwọn aláìsàn tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ tó díjú gan-an fún níbi ikùn, ohun tó parí èrò sí ni pé: “Àwọn aláìsàn tí wọn ò fàjẹ̀ sí lára ò pa dà níṣòro tó àwọn tó gbẹ̀jẹ̀, iye tó sì kú lára àwọn tí kò gbẹ̀jẹ̀ ò tó ti àwọn tó gbẹ̀jẹ̀.”
“Àwọn aláìsàn tí wọn ò fàjẹ̀ sí lára ò pa dà níṣòro tó àwọn tó gbẹ̀jẹ̀, iye tó sì kú lára àwọn tí kò gbẹ̀jẹ̀ ò tó ti àwọn tó gbẹ̀jẹ̀.”—Dókítà Tommaso Campagnaro, oníṣẹ́ abẹ ní Verona University Hospital
Dókítà Campagnaro àtàwọn míì tí wọ́n sọ̀rọ̀ níbi àpérò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní tààràtà torí bí wọ́n ṣe ṣí àwọn dókítà lójú pé kí wọ́n wá àwọn ìtọ́jú míì dípò lílo ẹ̀jẹ̀. Anna Aprile, tó jẹ́ àgbà ọ̀mọ̀wé nínú òfin ìmọ̀ ìṣègùn ní Yunifásítì Padua, sọ pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mú kí ọ̀rọ̀ yìí wá sójútáyé, ìyẹn ẹ̀tọ́ téèyàn ní láti sọ pé òun ò gbẹ̀jẹ̀, èyí sì ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn láti tún ọ̀rọ̀ yìí rò débi pé, ní báyìí a ti wá mọ bá a ṣe lè ṣọ́ ẹ̀jẹ̀ ẹni tá a bá ń tọ́jú lò.”
“A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mú kí ọ̀rọ̀ yìí wá sójútáyé, ìyẹn ẹ̀tọ́ téèyàn ní láti sọ pé òun ò gbẹ̀jẹ̀ . . . ”—Anna Aprile, àgbà ọ̀mọ̀wé nípa òfin ìmọ̀ ìṣègùn, Yunifásítì Padua
Oríṣiríṣi ẹ̀ka ìmọ̀ ìṣègùn làwọn tó sọ̀rọ̀ níbi àpérò náà ti wá, irú bí àwọn dókítà tó ń pa ara lókùú nígbà iṣẹ́ abẹ, àwọn dókítà tó ń tọ́jú ọkàn, àwọn obìnrin, ẹ̀jẹ̀, àrùn jẹjẹrẹ àtàwọn tó ń to eegun. Àmọ́ ohun kan náà ni gbogbo àpérò yẹn dá lé, ìyẹn ni pé: kí àwọn iléeṣẹ́ ìmọ̀ ìṣègùn, àwọn aṣòfin àti gbogbo aráàlú kọ́wọ́ ti ètò PBM nítorí pé àṣeyọrí táwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ń ṣe ń pọ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń tọ́jú àwọn aláìsàn.
Dókítà Weltert fi kún un pé: “Iṣẹ́ abẹ tó gbẹgẹ́ jù lọ tí dókítà lè ṣe lára èèyàn lèyí tí wọ́n bá ṣe lára òpó tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ jáde látinú ọkàn. . . . Tí wọ́n bá lè ṣe [irú ẹ̀] láìlo ẹ̀jẹ̀, á jẹ́ pé kò sóhun tí ò ṣeé ṣe.”
^ ìpínrọ̀ 4 Bí àpẹẹrẹ, níbi àpérò yẹn, wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní Ìwọ̀ Oòrùn Ọsirélíà, tí wọ́n sì gbé jáde nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn tó gbawájú jù lórí ọ̀rọ̀ ìfàjẹ̀sínilára, tí wọ́n pè ní Transfusion. Àwọn tó ṣèwádìí yẹn ṣàlàyé ohun tó jẹ́ àbájáde ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí wọ́n fi ọdún mẹ́fà ṣe láti fi ìtọ́jú ìṣègùn tó yarantí lélẹ̀ nípa títẹ̀lé ètò PBM. Wọ́n wo ìsọfúnni àwọn aláìsàn tí iye wọn jẹ́ 605,046 tí wọ́n ń gbàtọ́jú nílé ìwòsàn ńlá mẹ́rin. Wọ́n rí i pé nǹkan bí ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá àwọn tí wọ́n ń fi èròjà inú ẹ̀jẹ̀ tọ́jú tẹ́lẹ̀ ni wọn ò fi tọ́jú mọ́ báyìí. Lákòókò yẹn kan náà, iye àwọn tó ń kú nílé ìwòsàn fi nǹkan bí ìdá mẹ́ta dín kù sí ti tẹ́lẹ̀, nǹkan bí ìdá mẹ́fà lára àwọn aláìsàn ni kì í pẹ́ nílé ìwòsàn mọ́, iye àwọn tó kó àìsàn látara kòkòrò àrùn nílé ìwòsàn fi nǹkan bí ìdá márùn-ún lọ sílẹ̀, iye àwọn tó ń ní àìsàn ọkàn àti àrùn rọpárọsẹ̀ sì fi nǹkan bí ìdá mẹ́ta dín kù sí ti tẹ́lẹ̀. Bí wọ́n ṣe fi ètò PBM lọ́lẹ̀ yìí ti jẹ́ kí ara àwọn aláìsàn túbọ̀ yá, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lo èròjà ẹ̀jẹ̀ láti tọ́jú wọn mọ́, iye owó tí aláìsàn sì ń ná ti dín kù.