Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọ́fíìsì Olùpẹ̀jọ́ àti ilé ẹjọ́ Termini Imerese nílùú Sicily, ní Ítálì.

AUGUST 22, 2018
ÍTÁLÌ

Ilé Ẹjọ́ Kan Nílùú Sicily Túbọ̀ Fìdí Ẹ̀ Múlẹ̀ Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Pinnu Irú Ìtọ́jú Tí Wọ́n Fẹ́ Nílé Ìwòsàn

Ilé Ẹjọ́ Kan Nílùú Sicily Túbọ̀ Fìdí Ẹ̀ Múlẹ̀ Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Pinnu Irú Ìtọ́jú Tí Wọ́n Fẹ́ Nílé Ìwòsàn

Ní April 6, 2018, Ilé Ẹjọ́ Termini Imerese nílùú Sicily lórílẹ̀-èdè Ítálì dájọ́ pé dókítà oníṣẹ́ abẹ kan jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀daràn torí pé ó fipá fa ẹ̀jẹ̀ sí obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára. Wọ́n ní kí dókítà náà san ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé márùn-ún owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ($11,605 U.S.) fún obìnrin náà gẹ́gẹ́ bí owó gbà-máà-bínú, kó sì tún san ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mẹ́ta owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ($5,803 U.S.) fún ọkọ obìnrin náà tóun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Ítálì máa dájọ́ pé dókítà kan jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀daràn torí pé ó fi ẹ̀tọ́ tí aláìsàn ní lábẹ́ òfin dù ú, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohunkóhun tó fẹ́ kí ẹlòmíì ṣe sí ara òun.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ni pé ní December 2010, wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún arábìnrin tá à ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí níbi òróòro, àmọ́ àwọn ìṣòro kan jẹyọ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé léraléra ló ń sọ pé òun ò gba èròjà inú ẹ̀jẹ̀ sára, agbára ẹ̀ ò ká dókítà náà, ó sì fipá fa àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Dókítà tó ṣiṣẹ́ abẹ náà parọ́ pé adájọ́ ilé ẹjọ́ ló fún òun láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Nígbà tó yá, obìnrin náà àti ọkọ ẹ̀ fẹjọ́ sun Ọ́fíìsì Olùpẹ̀jọ́. Ilé ẹjọ́ sì pinnu pé “tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan bá ti dàgbà tó lábẹ́ òfin, tó sì ní làákàyè tó, . . . dókítà ò gbọ́dọ̀ fún un nírú ìtọ́jú yìí” tí onítọ̀hún bá ti lóhun ò fẹ́.

Ilé ẹjọ́ tún kéde pé Òfin Orílẹ̀-èdè Ítálì ò fàyè gbà á kí dókítà fipá fún ẹnì kan ní irú ìtọ́jú kan pàtó tó bá ti lóun ò fẹ́, kódà kí dókítà sọ pé ó dáa kó gba irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀. Bí ilé ẹjọ́ náà ṣe sọ, “ti pé dókítà rí i pé ìtọ́jú kan pọn dandan . . . kì í ṣe àwáwí láti fipá mú kí aláìsàn gba ìtọ́jú tó ti fara balẹ̀ ṣàlàyé lọ́nà tó ṣe kedere pé òun ò fẹ́.”

Daniele Rodriguez, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ìṣègùn Lábẹ́ Òfin àti Ìlànà Ìtọ́jú ní Yunifásítì Padua, tún jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń jábọ̀ lórí ẹjọ́ náà. Ó kíyè sí i pé “[àpilẹ̀kọ] 32 nínú Òfin [Ítálì] jẹ́ kó ṣe kedere pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé òun ò gba irú ìtọ́jú kan pàtó. Òfin sọ pé ‘a ò gbọ́dọ̀ fipá mú ẹnikẹ́ni láti gba irú ìtọ́jú kan pàtó àfi tí òfin bá fọwọ́ sí i.’” Amòfin kan lórílẹ̀-èdè Ítálì, tó sì tún jẹ́ ògbóǹkangí nínú òfin tó jẹ mọ́ ìlera, tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Luca Benci sọ̀rọ̀ lórí ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe, ohun tó kọ nínú ìwé Quotidiano Sanità (Health Daily) rèé: “Kò sí òfin tó sọ pé ó pọn dandan kí aláìsàn gba ẹ̀jẹ̀ sára tó bá lóun ò fẹ́. Ẹ̀tọ́ tí aláìsàn ní láti sọ pé òun ò gba irú ìtọ́jú kan borí ohun gbogbo.”

Ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń jẹ́ Marcello Rifici sọ pé: “Inú wa dùn láti rí i pé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ dá yìí bá ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé nílẹ̀ Yúróòpù mu, bí èyí tó hàn nínú àwọn ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ti dá, tó jẹ́ kó ṣe kedere pé gbogbo aláìsàn ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu irú ìtọ́jú tí wọ́n fẹ́. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, lọ́dún 2017, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Ítálì ṣe òfin 219/2017, tí wọ́n mọ̀ sí ‘Òfin Ohun Tí Mo Fẹ́,’ (ìyẹn Living Will Law) àwọn ìlànà inú òfin yẹn sì bá ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe yìí mu.”

Òmíì lára àwọn agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń jẹ́ Lucio Marsella tún sọ pé: “Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe yìí máa ṣèrànwọ́ fún gbogbo àwọn dókítà onígboyà tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tọ́jú àwọn aláìsàn láìfi ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti yan ìtọ́jú tí wọ́n fẹ́ dù wọ́n.”