Ítálì
Lórílẹ̀-Èdè Ítálì, Wọ́n Ṣí Aṣọ Lójú Àmì Tó Ń Ránni Létí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Ẹgbẹ́ Òṣèlú Násì àti Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ Ṣe Inúnibíni Sí
Ètò kan wáyé ní abúlé Risiera di San Sabba ní ìlú Trieste, lórílẹ̀-èdè Ítálì, ní ìrántí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣenúnibíni sí jákèjádò ilẹ̀ Yúróòpù.
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Ítálì Fọwọ́ Sí I Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Yan Ìtọ́jú Ìṣègùn Tó Wù Wọ́n
Wọ́n dájọ́ kan láìpẹ́ yìí tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ará wa lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu irú ìtọ́jú tí wọ́n fẹ́
Ọ̀pọ̀ Dókítà Nífẹ̀ẹ́ sí Títọ́jú Aláìsàn Láìlo Ẹ̀jẹ̀ Níbi Àpérò Pàtàkì Méjì Táwọn Onímọ̀ Ìṣègùn Ṣe Lórílẹ̀-Èdè Ítálì
A lo ìbi àpérò méjì láti pèsè ìsọfúnni tuntun nípa ìtọ́jú ìṣègùn láìlo ẹ̀jẹ̀ fún àwọn dókítà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Lẹ́yìn náà, àwọn dókítà tó ń fún èèyàn láwọn oògùn tó ń dín ìrora kù àtàwọn oníṣẹ́ abẹ sọ ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n tọ́jú àwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ilé Ẹjọ́ Kan Nílùú Sicily Túbọ̀ Fìdí Ẹ̀ Múlẹ̀ Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Pinnu Irú Ìtọ́jú Tí Wọ́n Fẹ́ Nílé Ìwòsàn
Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Ítálì máa dájọ́ pé dókítà kan jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀daràn torí pé ó fi ẹ̀tọ́ tí aláìsàn ní lábẹ́ òfin dù ú, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé torí ohun téèyàn gbà gbọ́, èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohunkóhun tó fẹ́ kí ẹlòmíì ṣe sí ara òun.
Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Luca P. Weltert, M.D.
“Èrò àwọn dókítà nípa fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára àti ọwọ́ tí wọ́n fi mú un ti wá yàtọ̀ gan-an báyìí. Ó ti wá ṣe kedere pé wọn kì í fẹ́ fa ẹ̀jẹ̀ síni lára mọ́, kì í wá ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń tọ́jú nìkan o, àtàwọn míì kárí ayé. Ìdí sì ni pé ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló ti wà báyìí pé àwọn tí wọn ò fa ẹ̀jẹ̀ sí lára máa ń ṣe dáadáa lẹ́yìn ìtọ́jú ju àwọn tó gbẹ̀jẹ̀ lọ.”
Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Ọ̀jọ̀gbọ́n Antonio D. Pinna, M.D.
“Mi ò rò pé ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn jẹ́ ìṣòro rárá. Torí pé, àwọn kan tí kì í ṣe ajẹ́rìí pàápàá kì í fẹ́ gbẹ̀jẹ̀.”
Àpérò Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Wáyé ní Yunifásítì Padua Láti Jíròrò Ìtẹ̀síwájú Tó Ti Bá Ọ̀rọ̀ Títọ́jú Aláìsàn Láìlo Ẹ̀jẹ̀
Ọ̀pọ̀ ló gbà pé fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára ò léwu, wọ́n sì gbà pé òun nìkan lọ̀nà àbáyọ fáwọn aláìsàn tí ọ̀rọ̀ ìtọ́jú wọn tàbí iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fẹ́ ṣe díjú. Àmọ́ púpọ̀ nínú àwọn tó sọ̀rọ̀ níbi àpérò náà ni kò fara mọ́ èrò yẹn.
Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Ọ̀jọ̀gbọ́n Massimo P. Franchi, M.D.
“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an lẹ́nu iṣẹ́ mi débi pé mo ti wá mọ àwọn ọ̀nà ti mo lè gbà tọ́jú aláìsàn lọ́nà ti ìgbàlódé láìlo ẹ̀jẹ̀.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Kí Ará Tu Àwọn Tó Wá Ibi Ìsádi Wá Sí Yúróòpù
Àwọn tó ń bójú tó àgọ́ àwọn tó ń wá ibi ìsádi ní Yúróòpù mọyì bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ran àwọn olùwá ibi ìsádi lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.