FEBRUARY 18, 2019
JÁMÁNÌ
Ìlú Munich Ṣàfihàn Bí Ìjọba Násì Ṣe Pọ́n Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lójú
Àjọ kan tí wọ́n ń pè ní Munich Documentation Centre for the History of National Socialism ṣètò àkànṣe kan ní September 26, 2018, sí January 6, 2019, káwọn èèyàn lè mọ ohun ti ìjọba Násì fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí lásìkò tí wọ́n ń ṣàkóso. Kò ní yà yín lẹ́nu pé orí ilẹ̀ kan náà tí oríléeṣẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Násì wà nígbà yẹn lọ́hùn-ún ni àjọ yìí kọ́ ọ́fíìsì wọn sí.
Nígbà tí wọ́n ń ṣayẹyẹ ìṣílé ọ́fíìsì tuntun náà, Ọ̀mọ̀wé Hans-Georg Küppers tó jẹ́ abẹnugan nípa àṣà àti ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Munich ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ṣètò ìran àpéwò náà, ó ní: “Ó ṣe pàtàkì ká ṣe àkànṣe ètò yìí torí kì í ṣèní, kì í ṣàná làwọn èèyàn kan ti ń sọ pé kò sóòótọ́ nínú ìtàn tó sọ pé ìjọba Násì pọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú, wọ́n ní irọ́ funfun báláú ni. . . . Torí náà, a fẹ́ káwọn èèyàn lóye pé òótọ́ lọ̀rọ̀ náà, wọ́n á sì kà nípa àwọn tí ìjọba pọ́n lójú.”
Wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ohun tí ìjọba Násì fojú àwọn arákùnrin wa rí lásìkò yẹn, wọ́n ṣàlàyé bí wọ́n ṣe fìgboyà hàn, tí wọn ò sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn, tí wọ́n sì fara dà á. Ọgọ́ta (60) làwọn nǹkan tó dà bíi pátákó tí wọ́n kọ àwọn ìtàn náà sí, wọ́n sì gbé wọn kọ́ sára ògiri. Ìrírí Martin àti Gertrud Pötzinger wà nínú ọ̀kan lára ohun tí wọ́n gbé kọ́ náà, wọ́n sọ bí ìjọba ṣe mú àwọn méjèèjì, tí wọ́n sì fi wọ́n sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó yàtọ̀ síra. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò ju oṣù mélòó kan péré tí wọ́n ṣègbéyàwó. Ọdún mẹ́sàn-án gbáko ni wọn ò fi fojú kan ara wọn. Àwọn méjèèjì la ìpọ́njú yẹn já, Arákùnrin Pötzinger sí wà di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó yá.
Òmíràn ni ti Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Therese Kühner. Ọdún 1929 ló di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, (Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì là ń pè wọ́n nígbà yẹn). Nígbà tí ìjọba Jámánì fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, arábìnrin yìí yọ̀ǹda pé káwọn ará máa ṣèpàdé nínú ilé òun láìjẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń dọ́gbọ́n tẹ àwọn ìwé wa nínú ilé rẹ̀. Lẹ́yìn tí àṣírí tú sí ìjọba Násì lọ́wọ́, wọ́n mú Therese, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án pé “ó ń tẹ ìwé tó ta ko ìjọba, ó ń pín ìwé náà kiri, ó sì ń dá ojora sílẹ̀ fáwọn ọmọ ogun ìjọba.” Láìka gbogbo ohun tí wọ́n fojú Arábìnrin Kühner rí, kò bọ́hùn, ṣe ló di ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú títí dójú ikú. October 6, 1944 ni wọ́n pa á.
Ohun míì téèyàn máa rí kà ni báwọn ará wa ṣe pinnu pé àwọn ò ní dá sọ́rọ̀ ìṣèlú àti ogun, tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ́rí fún Hitler. Ìpinnu wọn yẹn ló mú kí ìjọba dìídì dájú sọ wọ́n, tí wọ́n sì fimú wọn dánrin.
Lọ́dún 1934, Hitler búra pé òun máa rí i dájú pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan lórílẹ̀-èdè náà mọ́. Ó sọ pé: “Àwọn èèyànkéèyàn yìí máa pòórá bí isó nílẹ̀ Jámánì!” Kó lè mú ọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣẹ, Hitler ṣe baba-ńlá inúnibíni sáwọn ará wa, àmọ́ wọ́n fara dà á. Ibo lọ̀rọ̀ náà wá yọrí sí? Hitler àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ ni ò sí mọ́, àmọ́ àwọn ará wa ṣì wà nílẹ̀ Jámánì digbí, kódà wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún kan àti márùndínláàádọ́rin (165,000). A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó sọ ìmọ̀ràn wọn dòfo, torí pé báwọn èèyàn tiẹ̀ ń pọ́n wa lójú, Ọlọ́run mú ká nírètí tí kì í “yọrí sí ìjákulẹ̀.”—Róòmù 5:3-5.