Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 21, 2016
JÁMÁNÌ

Ayẹyẹ Ìrántí Ọdún Tá A Dá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Sílẹ̀ ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Brandenburg—Ọ̀rọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ló Dá Lé Lọ́dún Yìí

Ayẹyẹ Ìrántí Ọdún Tá A Dá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Sílẹ̀ ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Brandenburg—Ọ̀rọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ló Dá Lé Lọ́dún Yìí

ÌLÚ SELTERS, lórílẹ̀-èdè Jámánì—Ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n sọ jù níbi ayẹyẹ ìkọkànléláàádọ́rin [71] tó wáyé ní April 24, 2016 láti fi rántí ọdún tí wọ́n dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀ ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Brandenburg-Görden.

Daniela Trochowski, tó jẹ́ Aṣojú Ìjọba lórí ọ̀rọ̀ Ìnáwó ní Brandenburg sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ náà.

Iléeṣẹ́ Brandenburg Memorials Foundation (ìyẹn, Stiftung Brandenburgische Gedenkstätten) ló ṣe onígbọ̀wọ́ ayẹyẹ yìí. Ìsàlẹ̀ nínú Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Brandenburg an der Havel (tí àwòrán rẹ̀ wà lókè yìí) ni wọ́n ti ṣe é, nǹkan bíi àádọ́rùn-ún [90] kìlómítà ni ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wà sí ìwọ̀ oòrùn ìlú Berlin. Àwọn tó wá síbi ayẹyẹ náà lé ní igba [200]. Daniela Trochowski, tó jẹ́ Aṣojú Ìjọba lórí ọ̀rọ̀ Ìnáwó ní Brandenburg sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Ó sọ pé: “Wọ́n fìyà ikú jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbí . . . torí pé wọn ò ‘Kókìkí Hitler’ torí ó ta ko ẹ̀sìn wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé wọn ò lọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ orílẹ̀-èdè, wọ́n sì kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun.”

Sigurd Speidel wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí àwọn ọmọ ogun Násì pa ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Brandenburg-Görden.

Nígbà ayé ìjọba Násì, Adolf Hitler tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Jámánì nígbà yẹn sọ pé ‘ìran tó yẹ kó pa run’ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nínú èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] tí wọ́n pa ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Brandenburg-Görden (bí wọ́n ṣe ń pè é nígbà ayé ìjọba Násì) láàárín ọdún 1940 sí 1945, mẹ́tàdínláàádóje [127] nínú wọn ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ni àwùjọ tó pọ̀ jù tí wọ́n pa níbẹ̀.

Níbi ayẹyẹ tí wọ́n ṣe ní April 24 yẹn, Jochen Feßenbecker, tó jẹ́ aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Jámánì fọ̀rọ̀ wá Ọ̀gbẹ́ni Werner Speidel lẹ́nu wò. Ọ̀gbẹ́ni Speidel sọ pé Sigurd ẹ̀gbọ́n òun wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n pa ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Brandenburg-Görden. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] ni Sigurd nígbà tí ilé ẹjọ́ àwọn ológun rán an lọ sẹ́wọ̀n. Kò pé oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn, ní January 27, 1943, tí wọ́n fi bẹ́ ẹ lórí. Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Feßenbecker ń fọ̀rọ̀ wá Ọ̀gbẹ́ni Speidel lẹ́nu wò, ó ka lẹ́tà ìdágbére tí Sigurd kọ ní wákàtí mélòó kan kí wọ́n tó pa á. Ọ̀gbẹ́ni Speidel sọ bó ṣe rí lára ìdílé wọn nígbà tí wọ́n ń ka ọ̀rọ̀ tí Sigurd fi dágbére fún wọn, ó ní: “Ìbẹ̀rù ò bò wá bá a ṣe ń ka lẹ́tà yìí. Kàkà tá a fi máa bẹ̀rù, ṣe ni inú wa ń dùn sí Sigurd pé kò yẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀ títí dójú ikú.”

Lẹ́tà ìdágbére tí Sigurd Speidel kọ sí ìdílé rẹ̀ rèé. Ohun tó kọ sí ibi tó funfun lókè yẹn nìyí: “Gbogbo nǹkan ni mo ti fara dà, mi ò sì bọ́hùn rárá, ṣe ni mo dúró digbí bí ògiri.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Jámánì: Wolfram Slupina, 49-6483-41-3110