Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 10, 2019
JAPAN

Àkúnya Omi Ṣọṣẹ́ Lórílẹ̀-Èdè Japan

Àkúnya Omi Ṣọṣẹ́ Lórílẹ̀-Èdè Japan

Ní August 28, ọdún 2019, òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tó rọ̀ ní àgbègbè Kyushu lórílẹ̀-èdè Japan fa àkúnya omi tó lágbára gan-an. Ṣe làwọn odò kún àkúnya, àwọn àgbègbè míì sì léwu torí pé ó ṣeé ṣe kí àwọn òkè ya lulẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sọ fún àwọn èèyàn tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800,000) pé kí wọ́n kúrò lágbègbè yẹn. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Japan ròyìn pé, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin méjìlélọ́gọ́rin (82) ló fi ilé wọn sílẹ̀. Ìròyìn tó dé kẹ́yìn sọ pé ogójì (40) ilé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló bà jẹ́ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ bà jẹ́ púpọ̀.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì náà dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sílẹ̀ kí wọ́n lè bójú tó àwọn akéde tí àjálù náà kàn. Àwọn alábòójútó àyíká, àwọn alàgbà àtàwọn akéde pèsè ìtùnú àti ìṣírí látinú Bíbélì, wọ́n sì fún wọn láwọn nǹkan míì bí oúnjẹ àti aṣọ. Inú wa dùn pé ìfẹ́ ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́.​—2 Kọ́ríńtì 8:4.