Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọ̀kan nínú ilé àwọn arákùnrin wa tí ìjì náà bà jẹ́

NOVEMBER 18, 2019
JAPAN

Ìjì Líle Tí Wọ́n Pè Ní Typhoon Bualoi Ṣọṣẹ́ Lórílẹ̀-Èdè Japan

Ìjì Líle Tí Wọ́n Pè Ní Typhoon Bualoi Ṣọṣẹ́ Lórílẹ̀-Èdè Japan

Ní October 25 àti 26, 2019, ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Typhoon Bualoi ṣọṣẹ́ ní apá ìlà oòrùn etíkun Japan. Ohun tó gba àfiyèsí ni pé, ìjì yìí ni ìkẹta nínú àwọn ìjì tó jà ní ìlà oòrùn Japan láti September, lẹ́yìn tí ìjì líle tí wọ́n pè ní Typhoon Faxai àti Hagibis jà. Ìjì líle tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jà yìí mú kí àwọn odò kún àkúnya, èyí sì fa ọ̀pọ̀ omíyalé ní agbègbè náà. Ó kéré tán, ilé mọ́kànlélọ́gọ́rin (81) tó jẹ́ tàwọn ará wa ló bà jẹ́. A ò gbọ́ pé ará wa kankan kú, àmọ́ arábìnrin kan fara pa. Ìjì yìí ti kó àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Chiba sí ìdààmú gan-an.

Ìgbìmọ̀ mẹ́ta tó ń pèsè ìrànwọ́ nígbà àjálù ló ṣètò ìrànwọ́ láwọn agbègbè yìí nígbà tí ìjì Faxai àti Hagibis jà, àwọn náà ló sì ń pèsè ìrànwọ́ báyìí lẹ́yìn tí ìjì Bualoi jà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Japan ń ti àwọn ìgbìmọ̀ yìí lẹ́yìn kí wọ́n lè pèsè ìtọ́jú ní kíákíá fáwọn ará wa. Wọ́n ń bá wọn tún àyíká wọn ṣe, wọ́n ń pèsè àwọn oògùn tó ń pa kòkòrò, wọ́n sì ń tún àwọn ilé wọn tó bà jẹ́ ṣe. Àwọn alábòójútó àyíká ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fún àwọn ará ní ìṣírí, kí wọ́n sì tù wọ́n nínú.

Lákòókò tí nǹkan le yìí, à ń gbàdúrà fún àwọn ará wa tó wà ní Japan, a sì mọ̀ pé Jèhófà máa bójú tó àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tí “àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn” nítorí àjálù yìí.—Sáàmù 34:18.