SEPTEMBER 17, 2019
JAPAN
Ìjì Líle Tó Ń Jẹ́ Faxai Ṣọṣẹ́ ní Orílẹ̀-Èdè Japan
Ní September 9, 2019 ìjì líle tó ń jẹ́ Faxai jà nítòsí Tokyo, lórílẹ̀-èdè Japan. Afẹ́fẹ́ ìjì náà lágbára débi pé ó fẹ́ dé ibi tó jìnnà tó ọgọ́sàn-án (180) kìlómítà láàárín wákàtí kan péré, ó sì ba iná mànàmáná ilé tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ọgọ́rin (580,000) jẹ́. Ó kéré tán èèyàn mẹ́ta ló pàdánù ẹ̀mí wọn.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Japan ròyìn pé kò sí akéde kankan tó kú, àmọ́ méje lára àwọn ará wa fara pa. Àyẹ̀wò tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe fi hàn pé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti márùndínlọ́gọ́rùn-ún (895) ilé àwọn ará ló bà jẹ́, Gbọ̀ngàn Ìjọba méjìdínlọ́gbọ̀n (28) àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan tó wà ni Chiba sì bà jẹ́.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣì ń ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí ìjì náà bà jẹ́ kí wọ́n lè pèsè ohun táwọn ará nílò. A gbàdúrà pé kí Jèhófà, “Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìfaradà àti ìtùnú” máa tu àwọn ará wa yìí nínú, kó sì dúró tì wọ́n lásìkò àjálù yìí.—Róòmù 15:5