Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 23, 2019
JAPAN

Ìjì Líle Tó Ń Jẹ́ Hagibis Rọ́ Lu Orílẹ̀-Èdè Japan

Ìjì Líle Tó Ń Jẹ́ Hagibis Rọ́ Lu Orílẹ̀-Èdè Japan

Ìjì líle tí wọn ń pè ní Hagibis rọ́ lu orílẹ̀-èdè Japan ní October 12 sí 13, 2019. Ó kéré tán, èèyàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77) ló kú nínú ìjì líle yìí, ó sì fa àkúnya omi tó pọ̀ gan-an. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé ni ìjì yìí ò jẹ́ kí iná mànàmáná àti omi ẹ̀rọ dé ọ̀dọ̀ wọn mọ́. Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Japan ṣì ń wá àwọn tó sọnù. Ìjì líle yìí ni wọ́n sọ pé ó jẹ́ èyí tó lágbára jùlọ nínú àwọn ìjì tó tíì jà ní Japan láti ọdún 1958. Òjò tí ìjì náà fà mu èèyàn dé ìbàdí làwọn ibì kan.

A dúpẹ́ pé kò sí ìkankan nínú àwọn ará wa tó sọnù tàbí tí ìjì yìí pa, àmọ́ àwọn ará mẹ́wàá fara pa díẹ̀. Bákan náà, ilé tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti igba (1200) tó jẹ́ ti àwọn ará ló bà jẹ́. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bà jẹ́ jẹ́ mẹ́tàlélógún (23) tí mẹ́ta nínú wọn kò sì ṣeé lò báyìí nítorí omi ti ya wọ ibẹ̀ àti pé iná mànàmáná wọn ti bà jẹ́. Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà nílùú Tochigi náà bà jẹ́ díẹ̀.

A ti ṣètò àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ní ìpínlẹ̀ Fukushima àti Nagano. Tí iṣẹ́ náà bá ṣe ń fẹjú sí i, ó ṣeéṣe ká tún ṣètò àwọn ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ púpọ̀ sí i. A ti ń pèsè oúnjẹ àti omi fún àwọn ará wa tí àkúnya omi náà ṣọṣẹ́ fún. A sì ti rán àwọn alábòójútó àyíká tó wà ní àwọn agbègbè yìí láti gba àwọn ara níyànjú kí wọn sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wọ́n nínú.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa báa lọ láti jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ará wa ní àkókò àdánwò líle koko yìí.​—Sáàmù 142:5.