JULY 23, 2020
JAPAN
Òjò Àrọ̀ọ̀rọ̀dá àti Omíyalé Bá Nǹkan Jẹ́ ní Gúúsù Orílẹ̀-èdè Japan
Níbẹ̀rẹ̀ oṣù July 2020, òjò ńlá kan rọ̀ débi pé ó fa omíyalé, ó sì mú kí ilẹ̀ ya ní Kyushu lórílẹ̀-èdè Japan. Àjálù yìí kan àwọn ará wa tó wà nílùú Minamata àti Hitoyoshi àtàwọn ará wa tó wà nílùú Omuta. Kò sí ìkankan nínú àwọn ará wa tó kú, àmọ́ arákùnrin kan àti arábìnrin wa kan fara pa díẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, omíyalé náà ba ilé méjìdínláàádọ́ta (48) tó jẹ́ ti àwọn ará wa jẹ́, ó sì tún ba Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì jẹ́. Ilẹ̀ tó ya tún ba Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì míì jẹ́.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Japan sọ pé kí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù tí wọ́n yàn nígbà àjàkálẹ̀ àrùn corona lọ ṣèrànwọ́ fáwọn ará ti omi ba ilé wọn jẹ́ nílùú Kyushu. Nígbà táwọn aṣojú Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ àtàwọn alábòójútó àyíká tó wà ní agbègbè yẹn gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, àwọn náà tètè ṣèrànwọ́ nígbà àjálù yìí.
Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà, “Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìfaradà àti ìtùnú,” túbọ̀ máa wà pẹ̀lú àwọn ará wa tí àjálù dé bá yìí.—Róòmù 15:5.