Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 24, 2017
JAPAN

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yọ̀ǹda Ara Wọn Láti Tún Ilé Tó Lé Ní 300 Ṣe Lẹ́yìn Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Wáyé ní Japan

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yọ̀ǹda Ara Wọn Láti Tún Ilé Tó Lé Ní 300 Ṣe Lẹ́yìn Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Wáyé ní Japan

Àwọn Ẹlẹ́rìí ń tún òrùlé ilé kan tó ti bà jẹ́ ṣe ní Koshi.

ÌLÚ EBINA, lórílẹ̀-èdè Japan—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Japan parí àtúnṣe tí wọ́n ń ṣe sí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ilé ó lé méjìdínlọ́gọ́ta [348] tó jẹ́ ti àwọn ará wọn. Ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé ní April 14 àti 16, 2016, nílùú Kumamoto lórílẹ̀-èdè Japan ló ba àwọn ilé náà jẹ́. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] làwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkọ́lé yìí kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. July 2016 sí March 2017 ni wọ́n fi ṣe é.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ, mọ́kàndínlọ́gọ́fà [119] lára wọn ló gba pé kí wọ́n kúrò nínú ilé wọn. Inú Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], ìyẹn ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn, ni wọ́n kọ́kọ́ kó àwọn tí ilé wọn bà jẹ́ sí, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn wá lọ palẹ̀ ilé àwọn èèyàn yìí mọ́.

Àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́fà ń ṣe òrùlé tuntun sórí ilé kan tó bà jẹ́ nílùú Chimachi.

Àwọn òṣìṣẹ́ ń tún ilé kan tó bà jẹ́ ṣe nílùú Mashiki.

July 25, 2016 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé níbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n tún àwọn ibi tó là lára ilé ṣe, wọ́n tún ilẹ̀ rẹ́, wọ́n ṣàtúnṣe àwọn ògiri inú ilé, òrùlé àtàwọn ẹ̀rọ omi tó bà jẹ́ nítorí ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé. Wọ́n tún fi ilẹ̀kùn tuntun, wíńdò àtàwọn ẹ̀rọ amúlétutù rọ́pò àwọn èyí tó ti bà jẹ́.

Nílùú Kikuchi, àwọn òṣìṣẹ́ ń yọ àwọn ibi tó fọ́ lára òrùlé kúrò, wọ́n sì ń fi tuntun rọ́pò rẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Minoru Kono, tó ń bá Ẹgbẹ́ Ológun orílẹ̀-èdè Japan ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí iṣẹ́ ìkọ́lé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí, ó ní: “Nínú iṣẹ́ tí mò ń ṣe, tó bá dọ̀rọ̀ ká gbẹ̀mí àwọn èèyàn là, a kì í fi nǹkan falẹ̀ rárá! Báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ò ṣe fi nǹkan falẹ̀ nìyẹn lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé nílùú Kumamoto nìyẹn, wọ́n yára lọ síbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ kí wọ́n lè ran àwọn tọ́rọ̀ kàn lọ́wọ́. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ń ṣe yìí, ó yà mí lẹ́nu gan-an pé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni mo rí níbẹ̀, tí wọ́n ń wá láti oríṣiríṣi ibi lórílẹ̀-èdè Japan kí wọ́n lè wá ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. Tọkàntọkàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó yọ̀ǹda ara wọn fi ṣiṣẹ́, wọn ò fi iṣẹ́ náà ṣeré rárá.”

Nílùú Uki, Ẹlẹ́rìí kan ń ti kọnkéré wọnú ilé kan tó ti bà jẹ́, kọnkéré yìí ni wọ́n máa fi tún ìpìlẹ̀ ilé náà ṣe.

Ichiki Matsunaga, agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Japan, sọ pé: “Láti oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ àjálù tó ṣẹlẹ̀ yìí ti ń tán lára wa, tá a sì ń pawọ́ pọ̀ kọ́lé pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé nílùú Kumamoto ṣèpalára fún. Báwọn ará wa ṣe ṣèrànwọ́ lẹ́yìn tí àjálù yìí wáyé ti gbé wa ró gan-an, orísun ìtùnú ló sì jẹ́ fún wa. Kò ṣeé fowó rà!”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Japan: Ichiki Matsunaga, +81-46-233-0005