SEPTEMBER 13, 2018
JAPAN
Ìjì Líle Jebi Jà ní Japan
Ní Tuesday, September 4, 2018, ìjì líle kan jà ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Japan, ó ti lé lógún ọdún tírú ẹ̀ ti jà kẹ́yìn nílẹ̀ náà. Àwọn aláṣẹ ní kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò níbi tí wọ́n wà. Bó sì ṣe máa ń rí lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí ìjì líle náà bà jẹ́ kì í ṣe kékeré.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Japan sọ pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ. Àmọ́ ó kéré tán, àwọn ará mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ló fara pa, ilé tó sì bà jẹ́ tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti méjìdínlógójì (538), ó kéré tán. Àyẹ̀wò àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe fi hàn pé Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rìnlélógójì (44) ló bà jẹ́.
Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù, tó wà ní ìlú Osaka àti ní Sakai ti jọ ń ṣiṣẹ́ lórí bí wọ́n á ṣe ṣèrànlọ́wọ́, títí kan bí wọ́n á ṣe tún àwọn ilé tó bà jẹ́ ṣe, tí wọ́n á sì bẹ àwọn tọ́rọ̀ náà kàn wò.
A dúpẹ́ pé Jèhófà mọ ìṣòro tí àwọn ará wa ń ní, ó sì ń lo ẹgbẹ́ ará láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Sáàmù 34:19.