Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 10, 2018
JAPAN

Ìjì Líle Trami: Ìjì Líle Tó Jà Lẹ́nu Àìpẹ́ Yìí ní Japan

Ìjì Líle Trami: Ìjì Líle Tó Jà Lẹ́nu Àìpẹ́ Yìí ní Japan

Ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Trami jà ní gúúsù ilẹ̀ Japan nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Sunday, September 30, 2018. Ọwọ́ ìjì náà lágbára gan-an, òjò tó sì rọ̀ pọ̀ púpọ̀. Àmọ́ ìjì náà bẹ̀rẹ̀ sí í rọlẹ̀ kó tó dé apá àríwá lópin ọ̀sẹ̀ náà. Nígbà tó fi máa dọjọ́ Monday, October 1, ó dé ìlú Tokyo. Èèyàn mẹ́ta ló kú, nǹkan bíi igba (200) ló fara pa, ó sì lé ní mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (1,300,000) ilé tí ìjì náà ba iná wọn jẹ́.

Ìròyìn tá a gbọ́ látọ̀dọ̀ àwọn alábòójútó àyíká fi hàn pé erékùṣù Okinawa, ní gúúsù ilẹ̀ Japan ni ìjì náà ti ba nǹkan jẹ́ jù. Àyẹ̀wò àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe láwọn àyíká mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà ní Okinawa àtàwọn ibi tó wà nítòsí fi hàn pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó kú nínú àjálù yìí, àmọ́ àwọn mẹ́sàn-án fara pa. Ìjì líle náà tún ba nǹkan bí ọgọ́fà (120) ilé àwọn ará wa jẹ́ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún ní erékùṣù Okinawa. Bákan náà, ọwọ́ ìjì yìí ba Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kànlélógójì (41) jẹ́ káàkiri àwọn agbègbè míì nílẹ̀ Japan.

Àwọn alábòójútó àyíká tó wà láwọn agbègbè yìí àtàwọn tó wà ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ ṣì ń ṣèwádìí kí wọ́n lè mọ bí àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe pọ̀ tó, wọ́n sì ń ṣètò bí àwọn ará á ṣe máa jọ́sìn Ọlọ́run nìṣó, kí wọ́n sì tún pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò fún wọn.

À ń gbàdúrà fún àwọn ara wa tí ìjì líle yìí kàn àtàwọn àjálù míì tó wáyé nílẹ̀ Japan. Ó dá wa lójú pé Baba wa ọ̀run máa tu ọkàn àwọn ará wa yìí lára, á sì mú kí wọ́n mọ́kàn le.—2 Tẹsalóníkà 2:17.