SEPTEMBER 28, 2018
JAPAN
Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Hokkaido,Japan
Ní September 6, 2018, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára wáyé ní Hokkaido, erékùṣù kan ní gúúsù orílẹ̀-èdè Japan. Ìmìtìtì ilẹ̀ náà gbẹ̀mí èèyàn mọ́kànlélógójì (41), ó sì ba iná ìjọba jẹ́ gan-an, èyí mú kó ṣòro láti rí ọkọ̀ èrò wọ̀, ó sì tún mú kó ṣòro láti kàn sí àwọn tó wà ní erékùṣù náà.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Japan so pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó bá ìmìtìtì ilẹ̀ náà lọ, àwọn ará wa méje ló fara pa. Ọgọ́rùn-ún (100) ilé àwọn ará wa àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rin ló bà jẹ́.
Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò pé kí àwọn ará kó oúnjẹ, omi àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì lọ fún àwọn ará tó wà lágbègbè tí àjálù yìí ti ṣẹlẹ̀. A ṣètò Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù láti wá bí àwọn ará wa níbẹ̀ ṣe máa rí àwọn nǹkan tí wọ́n máa nílò lọ́jọ́ iwájú.
Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa fún àwọn ará wa tó wà níbi tí àjálù yìí ti ṣẹlẹ̀ ní ìbàlẹ̀ ọkàn.—Fílípì 4:6, 7.