Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 12, 2018
JAPAN

Omíyalé Ba Nǹkan Jẹ́ ní Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Japan

Omíyalé Ba Nǹkan Jẹ́ ní Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Japan

Ó kéré tán, èèyàn mọ́kàndínláàádọ́sàn-án (169) ló ṣòfò ẹ̀mí ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Japan, kódà títí di báyìí, ó lé ní 255,000 agboolé tí ò rí omi tó dáa lò látàrí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tó fa omíyalé àti ilẹ̀ tó ya.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan lára àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ, a kó ọgọ́rùn-ún méjì (200) lára wa kúrò níbi tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀, arábìnrin wa kan sì ṣèṣe. Wọ́n tọ́jú arábìnrin wa tó fara pa yìí nílé ìwòsàn, ara rẹ̀ sì ti ń balẹ̀ báyìí. Ó kéré tán ilé mẹ́tàlélọ́gọ́rùn-ún (103) àwọn ará wa ló bà jẹ́, kódà ọ̀kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé ńṣe ló bà jẹ́ pátápátá. Kò mọ síbẹ̀ o, omíyalé yìí tún ba Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kànlá àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan jẹ́.

A dá ìgbìmọ̀ mẹ́rin sílẹ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù, kí wọ́n lè tu àwọn ará tọ́rọ̀ kàn nínú, kí wọ́n fún wọn níṣìírí nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò lójú ẹsẹ̀, irú bí oúnjẹ, aṣọ àti omi tó ṣeé mu. Àwọn ìgbìmọ̀ yìí á sì tún ṣètò ìrànlọ́wọ́ táwọn ará máa nílò lẹ́yìn náà, irú bí wọ́n ṣe máa fọ ilé àwọn ará, tí wọ́n á da oògùn apakòkòrò sí i, tí wọ́n á sì tún àwọn ibi tó bà jẹ́ níbẹ̀ ṣe.

À ń gbàdúrà fún àwọn ará wa tí àjálù yìí dé bá nílẹ̀ Japan bá a ṣe ń retí ìgbà tí Jésù máa fi agbára rẹ̀ fòpin sí gbogbo àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ láyé pátápátá.​—Mátíù 8:​26, 27.

 

Kà Sí I