Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Fọ́tọ̀ àwọn tó fara gbá nínú ẹjọ́ Gabunia

OCTOBER 24, 2017
JỌ́JÍÀ

Orílẹ̀-èdè Jọ́jíà Gbà Pé Àwọn Jẹ̀bi Nílé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù

Orílẹ̀-èdè Jọ́jíà Gbà Pé Àwọn Jẹ̀bi Nílé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù

Ní October 12, 2017, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR) sọ ìpinnu wọn pé àwọ́n ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ orílẹ̀-èdè Jọ́jíà nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́wàá tí wọ́n dá lẹ́jọ́ láìtọ́. Bí àpẹẹrẹ, nínú ẹjọ́ Gabunia and others v. Georgia, ìjọba gbà láti san EUR 800 (ìyẹn nǹkan bí ₦339,136) fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹlẹ́rìí tọ́rọ̀ kan torí bí wọ́n ṣe ṣàìtọ́ sí wọn, tí wọn ò sì bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n bó ṣe wà nínú abala kẹsàn-án àti ìkẹrìnlá nínú Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn.

Ní September 2005, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́wàá gbé ẹjọ́ lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR) torí ìwà ìkà táwọn olórí ẹ̀sìn àti ìjọba hù sí wọn lẹ́ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kódà, láti October 1999 sí November 2003 ni wọ́n ti ń ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Jọ́jíà. Àwọn aláàbò ìlú pàápàá lọ́wọ́ sí ìwà ìkà yìí yálà ní tààràtà tàbí nípa bí wọ́n ò ṣe dáàbò bò wá nígbà táwọn alátakò gbéjà kò wá.

Ṣáájú ẹjọ́ Gabunia, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá ẹjọ́ mẹ́ta tó le lòdì sí ìjọba ilẹ̀ Jọ́jíà. Nínú ìdájọ́ náà, Ilé Ẹjọ́ dẹ́bi fún ìjọba Jọ́jíà torí bí wọ́n ṣe kùnà láti dáàbò bo ẹ̀tọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní, tí wọ́n sì fàyè gba ìwà ìkà táwọn èèyàn ń hù sí wọn láàárín àkókò yẹn. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù wá parí ọ̀rọ̀ pé bí àwọn aláàbò ìlú ṣe dágunlá sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “fi hàn pé wọ́n lọ́wọ́ sí ìwà burúkú náà.” Wọ́n tún sọ pé: “Bí àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Jọ́jíà kò ṣe ṣe ohun tó yẹ láti pèsè ààbò ti mú kí àwọn ẹlòmíì máa hùwà ìkà sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri orílẹ̀-èdè náà.” Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù tún kíyè sí pé “ìgbìmọ̀ aṣòfin ìlú àtàwọn tó ń fíná mọ́ àwọn ajẹ́rìí jọ lẹ̀dí àpò pọ̀” àti pé àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Jọ́jíà “ṣègbè nínú àwọn ẹjọ́ tí wọ́n dá torí pé wọ́n ò wádìí ọ̀rọ̀ délẹ̀” kí wọ́n tó dájọ́.

Bí ìjọba ilẹ̀ Jọ́jíà ṣe tètè wá bẹ̀bẹ̀, tí wọ́n sì gbà pé àwọn jẹ̀bi gbogbo ohun táwọn ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló jẹ́ kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹrin tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù ì bá dá fún wọn; ìyẹn ì bá sì kó gbogbo ìdájọ́ mẹ́ta àkọ́kọ́ pọ̀ mọ́ ìkẹrin. Ní báyìí, a dúpẹ́ pé ìjọba àtàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò hùwà ìkà sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà. Wọ́n ti wá lómìnira ẹ̀sìn.