AUGUST 5, 2019
KAMẸRÚÙNÙ
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì Jáde Lédè Bassa ní Orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Bassa ní àpéjọ agbègbè tó wáyé nílùú Douala, lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù ní August 2, 2019. Ó gbà tó oṣù méjìdínlógún (18) kí iṣẹ́ tó parí lórí iṣẹ́ ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ yìí. Ìgbà àkọ́kọ́ sì nìyí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa tú Bíbélì sí èdè tí àwọn èèyàn Kamẹrúùnù ń sọ.
Arákùnrin Peter Canning, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ọ́fíìsì Kamẹrúùnù ló mú Bíbélì yìí jáde ní ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ agbègbè tó wáyé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní Logbessou. Ẹgbẹ̀rún méjì ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (2,015) èèyàn ló wà níbẹ̀.
Ṣáájú ká tó mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì yìí jáde, Bíbélì tí wọ́nwó, tó sì ṣòro lóye ní àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó ń sọ èdè Bassa ń lò. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè tó ṣiṣẹ́ lórí ìtumọ̀ Bíbélì yìí sọ pé: “Ìtumọ̀ Bíbélì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde yìí máa ran àwọn akéde lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì dáadáa. Ó tún máa fi kún ìfẹ́ tí wọn ní fún Jèhófà àti ètò rẹ̀.”
Àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) ló ń sọ èdè Bassa ní Kamẹrúùnù. Ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mẹ́sàn-án (1,909) akéde tó ń sọ èdè Bassa ló wà ní Kamẹrúùnù.
Ó dá wa lójú pé ìtumọ̀ Bíbélì tó ṣe kedere tó sì rọrùn lóye yìí máa ran àwọn tó ń kà á lọ́wọ́ láti rí i pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè.”—Hébérù 4:12.