Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Nínú fọ́tò iṣẹ́ ìkọ́lé tá a yà látòkè yìí, àwọn ọ́fíìsì ló wà lókè lápá ọ̀tún, àwọn ilé gbígbé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló sì wà lápá ìsàlẹ̀.

MARCH 22, 2019
KAMẸRÚÙNÙ

Ìròyìn: Iṣẹ́ Ti Ń Lọ Gan-an Lórí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tuntun ní Kamẹrúùnù

Ìròyìn: Iṣẹ́ Ti Ń Lọ Gan-an Lórí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tuntun ní Kamẹrúùnù

Lọ́dún tó kọjá, iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù. Bó ṣe wà nínú àwòrán tó wà lókè yìí, iṣẹ́ ti ń lọ lórí àwọn ilé gbígbé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àtàwọn ọ́fíìsì. A retí pé ọgọ́ta (60) èèyàn láá máa gbé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun yìí, ó sì máa ní àyè tó gba àwọn mọ́kànléláàádọ́rin (71) láti ṣiṣẹ́. Ètò tó wà nílẹ̀ fi hàn pé iṣẹ́ máa parí lórí àwọn ilé náà títí ìparí oṣù December 2019. Àwọn fọ́tò tó tẹ̀ lé e yìí máa jẹ́ kẹ́ ẹ rí ibi tí iṣẹ́ náà dé.

Àwòrán bí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ṣe máa rí tíṣẹ́ bá parí

 

July 2018: Lápá iwájú nínú àwòrán, wọ́n ń to ipele àkọ́kọ́ búlọ́ọ̀kù Ilé Gbígbé Kẹta.

August 2018: Ibi tí wọ́n fẹ́ mọ ògiri tó máa yí gbogbo ọgbà náà ká sí.

September 2018: Lápá iwájú nínú àwòrán, wọ́n parí títo búlọ́ọ̀kù àjà kìíní Ilé Gbígbé Kẹrin.

October 2018: Bí àbáwọlé ibi táwọn ọ́fíìsì wà ṣe máa rí, ibẹ̀ làwọn èèyàn máa kọ́kọ́ dé sí tí wọ́n bá ń bọ̀ ní ọ́fíìsì.

December 2018: Wọ́n ń bo òrùlé Ilé Gbígbé Kejì àti Ìkẹta lọ́wọ́.