Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 26, 2018
KAMẸRÚÙNÙ

Iṣẹ́ Ń Lọ Lọ́wọ́ Lórí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tuntun Tí À Ń Kọ́ ní Kamẹrúùnù

Iṣẹ́ Ń Lọ Lọ́wọ́ Lórí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tuntun Tí À Ń Kọ́ ní Kamẹrúùnù

Àádọ́ta (50) ni àwọn tó ń fi gbogbo àkókò wọn ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Douala, lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù. Láìpẹ́, wọ́n máa ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun, torí pé a máa tó kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun sí àdúgbò Logbessou, èyí tó máa rọ́pò àwọn ọ́fíìsì tí wọ́n ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ní àdúgbò Bonabéri. Ti pé a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun fi hàn pé ìlọsíwájú ń bá ọ̀rọ̀ ìjọsìn Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù. Lọ́dún 2017, ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000) èèyàn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi, iye yẹn sì ju ìlọ́po méjì àwọn akéde lọ.

Àwọn ará wa ń ri ohun tí kò ní jẹ́ kí mànàmáná ṣọṣẹ́.

Ẹ̀gbẹ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan ni ibi tá a ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì náà sí wà. Àwọn òṣìṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò ìpìlẹ̀ ilé náà. Tá a bá ti kọ́ ilé náà tán, àwọn ilé gbígbé tó wà níbẹ̀ máa rí bíi tàwọn ilé tó wọ́pọ̀ ládùúgbò náà, àwọn ọ́fíìsì sì máa wà lọ́tọ̀ bó ṣe wà nínú fọ́tò tó wà lókè yìí. Ètò tá a ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni pé, títí ìparí ọdún 2019, ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa lè kó lọ síbẹ̀.

Gilles Mba, tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Kamẹrúùnù, tó ń bá Ẹ̀ka Tó Ń Gbéròyìn Jáde ṣiṣẹ́, sọ pé, “Ó wú wa lórí láti rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n ti yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé náà, táwọn náà ní irú ẹ̀mí tí Aísáyà ní.” (Aísáyà 6:8) Ó fi kún un pé, “Bí iṣẹ́ ṣe ń lọ ní pẹrẹu yìí jẹ́ kóríyá fún gbogbo àwa tá à ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì láti tẹra mọ́ṣẹ́. Ara wa ti wà lọ́nà láti bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ọ́fíìsì tuntun tá à ń kọ́ yìí fún ète tá a fi ń kọ́ ọ, ìyẹn láti bọlá fún orúkọ Jèhófà.”

Díẹ̀ lára àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (2,800) tó wá síbi àkànṣe ìpàdé tí wọ́n ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé náà.