Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Aṣáájú-ọ̀nà ni Arákùnrin àti Arábìnrin Mudaheranwa, wọ́n ń lọ síbi iṣẹ́

APRIL 6, 2020
KÁNÁDÀ

Ọkàn Wọn Balẹ̀ Lásìkò tí Àrùn COVID-19 Ń Jà

Ọkàn Wọn Balẹ̀ Lásìkò tí Àrùn COVID-19 Ń Jà

Arákùnrin Jean-Yves Mudaheranwa àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Vasthie wà lára àwọn oníṣègùn tó ń bójú tó àwọn tó ní àrùn Corona nílùú Montreal lórílẹ̀-èdè Kánádà. Arákùnrin Mudaheranwa jẹ́ dókítà tó ń tọ́jú àwọn tó níṣòro èémí, ọ̀kan lára ilé ìwòsàn tó wà nílùú Montreal ló sì ti ń ṣiṣẹ́. Ní ti ìyàwó rẹ̀, nọ́ọ̀sì ni, ọ̀kan lára ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó ní àrùn COVID-19 lòun ti ń ṣiṣẹ́ ní tiẹ̀. Ẹ̀yìn náà mọ bí àrùn yìí ṣe ń mú káwọn èèyàn kọ́kàn sókè, àmọ́ ọ̀kan tọkọtaya yìí balẹ̀ torí pé Jèhófà ń fún wọn lókun, ó sì ń mú kí “ayọ̀ kún inú ọkàn” wọn bó ti ṣèlérí nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.​—Àìsáyà 65:14.

Arákùnrin Mudaheranwa sọ pé: “Ńṣe lẹ̀rù ń bá àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, bóyá ni mo rí kí wọ́n bẹ̀rù bẹ́ẹ̀ rí.” Kí nìdí tí òun àti ìyàwó rẹ̀ ò fi bẹ̀rù? Arábìnrin Mudaheranwa sọ pé: “Bá a ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́ wà lára ohun tó mú kí ọkàn wa balẹ̀. A ṣàṣàrò lórí àmì tí Bíbélì sọ pé a fi máa mọ̀ pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, a sì rán ara wa létí ìlérí Jèhófà pé òun máa wà pẹ̀lú wa, òun ò sì ní fi wá sílẹ̀. Àdúrà tún wà lára ohun tó fi wá lọ́kàn balẹ̀. Kí n tó kúrò nílé lọ síbi iṣẹ́, mo kọ́kọ́ máa ń gbàdúrà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kára tù mí pẹ̀sẹ̀.”

Arákùnrin àti arábìnrin Mudaheranwa dara pọ̀ mọ́ àwọn ará yòókù nípàdé látorí ẹ̀rọ

Arákùnrin Mudaheranwa sọ pé: “Orílẹ̀-èdè Rùwáńdà ni mo ti wá, ojú mi sì rí màbo nígbà ogun kan tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa odindi ẹ̀yà kan run. Lórílẹ̀-èdè Kánádà tá a wà yìí, kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀, téèyàn ò bá sì ṣọ́ra èèyàn lè má rántí pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí. Kí n sòótọ́, kì í ṣe ìgbà gbogbo ni mo máa ń rántí pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé. Àmọ́, àrùn tó gbòde yìí ti mú kó túbọ̀ dá mi lójú pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ó ti mú kí n túbọ̀ mọyì Bíbélì, ó sì ti mú kí n túbọ̀ gbà gbọ́ pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan tó máa lọ láìṣẹ.”

Ojú tí Arákùnrin àti Arábìnrin Mudaheranwa fi wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ làwọn èèyàn Jèhófà níbi gbogbo láyé náà fi ń wò ó, ìyẹn sì mú kí ọkàn gbogbo wọn balẹ̀ láìka àrùn COVID-19 tó gbayé kan sí.​—Àìsáyà 48:18.