AUGUST 30, 2018
KÁNÁDÀ
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Kánádà Kọ̀ Láti Dá sí Ètò Ìyọlẹ́gbẹ́
Nínú ẹjọ́ Highwood Congregation of Jehovah’s Witnesses (Judicial Committee) v. Wall, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Kánádà fohùn ṣọ̀kan ní May 31, 2018 pé “àwọn ẹlẹ́sìn lómìnira láti pinnu ẹni tí wọ́n bá fẹ́ kó wà nínú ẹ̀sìn wọn, wọ́n sì lómìnira láti ṣe òfin tí wọ́n á máa tẹ̀ lé nínú ẹ̀sìn wọn,” èyí sì fi hàn pé wọ́n fọwọ́ sí i pé ilé ẹjọ́ ò gbọ́dọ̀ dá sí ètò táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nípa yíyọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́.
Ibi tí Ilé Ẹjọ́ náà parí èrò sí ni pé ìlànà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ ẹni tó dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì “kì í ṣe èyí tó ní ìkórìíra nínú, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń jẹ́ kí wọ́n lè ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè pa dà di ara Ìjọ,” Ilé Ẹjọ́ náà sì dájọ́ pé àwọn ilé ẹjọ́ yòókù ò gbọ́dọ̀ dá sí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, torí kì í ṣe nǹkan gbogboogbò, ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ni.
Adájọ́ Malcolm Rowe tó jẹ́ adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣàlàyé ìdí tí ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́sàn-án tó gbọ́ ẹjọ́ náà fi ṣèdájọ́ yẹn, ó ní: “Àwọn ìlànà àti òfin tí ẹ̀sìn pàtó kan ń tẹ̀ lé lè wé mọ́ ohun kan tí wọ́n gbà gbọ́, bá a ṣe rí i nínú ẹjọ́ yìí. Kò sí agbára lọ́wọ́ ilé ẹjọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò láṣẹ láti ṣèpinnu lórí irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn torí wọn ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́.”
Philip Brumley, tó jẹ́ agbẹjọ́rò àgbà fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Kánádà ṣe yìí mú kí wọ́n fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ilé ẹjọ́ gíga ní Ajẹntínà, Brazil, Hungary, Ireland, Ítálì, Peru, Poland àti Amẹ́ríkà, pé àwọn fọwọ́ sí i pé a lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká pinnu ẹni tó tóótun láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”—1 Kọ́ríńtì 5:11; 2 Jòhánù 9-11.