Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 11, 2019
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àkópọ̀ Ìpàdé Ọdọọdún ti 2019

Àkópọ̀ Ìpàdé Ọdọọdún ti 2019

Ní Saturday October 5, 2019, àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ṣe ìpàdé ọdọọdún wọn ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Newburgh nílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn ìpàdé náà, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ àwọn àsọyé tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun, iye àwọn tó wà níbẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,679), tó fi mọ́ àwọn tó wà ní àwọn ibi tí a ta àtagbà ètò náà sí. Díẹ̀ lára ohun tí wọ́n sọ nínú àsọyé wọn rèé. *

“Aṣáájú Kan Lẹ Ní, Kristi”

Arákùnrin Gerrit Lösch, tó jẹ́ alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ló sọ àsọyé àkọ́kọ́ tó dá lórí Mátíù 23:​10, ó sì rán wa létí pé Jésù Kristi ni aṣáájú wa, kì í ṣe èèyàn kankan.

Jèhófà Ń Lo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìrànwọ́ Wa Láti Ran Àwọn Míì Lọ́wọ́

Arákùnrin Stephen Lett ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ ọ̀làwọ́. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a le gbà fi hàn pé a lawọ́ ni pé ká máa ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Arákùnrin Lett ṣàkópọ̀ àwọn ohun tí àjálù fà àti àwọn ohun tá a ṣe ká lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́ lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2018 àti 2019. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900,000) àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí àjálù dé bá, ó sì lé ní ọgọ́rùn-ún méje (700) Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ilé àwọn ará tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) tó bà jẹ́. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhofà ná bílíọ̀nù méjìdínlógún náírà (ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta mílíọ̀nù owó dọ́là) lórí ìrànwọ́ nígbà àjálù.

Nínú àsọyé yìí, a wo àwọn fídíò tó fi hàn pé àwọn ará mọrírì ìrànwọ́ tí wọ́n rí gbà nígbà àjálù, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n sì fi dúpẹ́ oore.

‘‘Ọwọ́ Rere Ọlọ́run Wa Wà Lára Wa . . . Ẹ jẹ́ Ká Dìde, Ká sì Kọ́lé’ | Fídíò

Fídíò yìí jẹ́ ká rí i pé ilé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bójú tó kárí ayé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin (80,000). Ó tún jẹ́ ká rí àwọn ọ̀nà tá a gbà ń kọ́ àwọn ilé ìjọsìn wa, àwọn ọ̀nà tá a gbà ń bójú tó wọn àti bá a ṣe ń ṣàtúnṣe sí wọn.

Ìtàn Nípa Bá a Ṣe Ra Àwọn Ilé àti Ilẹ̀ | Fídíò

Ọ̀rọ̀ táwọn arákùnrin tó bá wa ra àwọn ilẹ̀ àti ilé sọ ló wà nínú fídíò yìí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti oríléeṣẹ́ wa ni wọ́n ń ràn lọ́wọ́, orúkọ wọn ni: Arákùnrin Max Larson, Arákùnrin George Couch, àti Arákùnrin Gilbert Nazaroff. Gbogbo wọn ló sọ bí wọ́n ṣe rí ọwọ́ Jèhófà nígbà tí wọ́n bá àjọ Watch Tower Bible and Tract Society ra àwọn ohun ìní náà.

À Ń Múra Sílẹ̀ Láti Kọ́ Ilé Tuntun | Fídíò

Nínú fídíò yìí, ètò Ọlọ́run sọ pé àwọn máa kọ́ ilé tuntun kan sí Ramapo, ní New York, ilé tuntun yìí á jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe fídíò púpọ̀ jáde. Ilẹ̀ tí a fẹ́ kọ́ ilé náà sí ò ju nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ta lọ sí oríléeṣẹ́ wa ní Warwick, nílùú New York. Wọ́n pinnu pé àwọn á bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé náà lọ́dún 2022, wọ́n á sì parí ẹ̀ ní December 2026. Tí iṣẹ́ ìkọ́lé náà bá ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu, a máa nílò àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó tó ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,500) lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.

Àwòrán Bẹ́tẹ́lì tuntun tí a fẹ́ kọ́ sí Ramapo, ní New York. Yàrá ìgbohùnsílẹ̀, àwọn ọ́fíìsì, ilé gbígbé àti ibi ìgbàlejò wà nínú àwòrán náà

Bí Àá Ṣe Máa Fi Fọ́ọ̀mù Ránṣẹ́ Nísìnyí | Fídíò

Fídíò yìí ṣàlàyé pé láti January 2020, àwọn akéde tó bá fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn máa láǹfààní láti kọ ọ̀rọ̀ sí fọ́ọ̀mù lórí ìkànnì jw.org, lẹ́yìn náà wọn á fi ránṣẹ́ sáwọn alàgbà ìjọ wọn kí wọ́n lè yẹ̀ ẹ́ wò.

Ọ̀nà Tuntun Tá A Lè Gbà Máa Gbọ́ Àwọn Ìtẹ̀jáde àti Orin Lórí JW.ORG

A ti lè rí àwọn àtẹ́tísí kan tó wà lórí ìkànnì jw.org lò báyìí lórí ètò ìṣiṣẹ́ Amazon Alexa tàbí Google Assistant.

Ìgbéjàko Láti Apá Àríwá

Arákùnrin David Splane ṣàlàyé òye tuntun tá a ní nípa àsọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ eéṣú tó wà ní Jóẹ́lì orí kejì. À ń fojú sọ́nà fún ìgbà tá a máa kọ́ nípa òye tuntun yìí ní kíkùn nígbà tó bá jáde nínú Ilé Ìṣọ́.

Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (Ẹ̀dà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́) láti ìwé Mátíù sí Ìṣe

Lo Bíbélì Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Láti Fi Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Arákùnrin Samuel Herd jẹ́ ká rí àwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń lo Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (Ẹ̀dà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́) tó wà lórí ìkànnì. Lẹ́yìn náà, wọ́n mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (Ẹ̀dà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́) láti ìwé Mátíù sí ìwé Ìṣe, tí a tẹ̀ jáde. Akéde kọ̀ọ̀kan lè béèrè fún ẹ̀dà tiẹ̀ láti ìjọ rẹ̀.

Iṣẹ́ Wà fún Wa Láti Ṣe!

Arákùnrin Anthony Morris jẹ́ ká mọ̀ pé ọwọ́ pàtàkì ló yẹ káwa Kristẹni tòótọ́ fi mú iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn ilé tí ètò Ọlọ́run ń lò kárí ayé ń ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí lẹ́yìn láti ṣètò iṣẹ́ ìwàásù kí wọ́n sì lè pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn èèyàn Jèhófà. Arákùnrin Morris sọ ohun kan tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 1977 tó yẹ ká fi sọ́kàn, ó ní: “Iṣẹ́ ìwàásù á máa lọ ní pẹrẹu nígbà tí ‘ìpọ́njú ńlá’ bá fi máa dé, á ti tẹ̀ síwájú ju tàtẹ̀yìnwá lọ níbi gbogbo láyé. Ìyàlẹ́nu pátápátá ni dídé Jésù Olúwa máa jẹ́, kódà, ó máa ya àwọn èèyàn Jèhófà lẹ́nu pàápàá, torí pé láìsí àní-àní yóò bá wọn lẹ́nu iṣẹ́ pẹrẹu!”

Kí Ló Yẹ Ká Bẹ̀rù?

Arákùnrin Mark Sanderson ṣàlàyé pé, “gbogbo orílẹ̀-èdè” máa kórìíra àwọn èèyàn Ọlọ́run bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 24:9) Àmọ́, Arákùnrin  Sanderson gbà wá níyànjú pé Jèhófà ló yẹ ká bẹ̀rù, kì í ṣe èèyàn.​—Sáàmù 111:10.

Lẹ́yìn náà, a wo fídíò kan tó jẹ́ ká rí bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe borí ìbẹ̀rù. Àsọyé àti fídíò yìí fún gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà níṣìírí pé kí wọ́n má bẹ̀rù èèyàn.

Ṣé Ojú Ẹ Ti Dá Pátápátá?

Arákùnrin Geoffrey Jackson ṣàlàyé ọ̀rọ̀ kan tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó túmọ̀ sí “kí ojú dá.” Ó tún jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká “máa ronú bó ṣe tọ́ nígbà gbogbo” (tó túmọ̀ sí “kí ojú dá pátápátá”) ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.​—1 Pétérù 1:13.

Ṣé O Máa Ṣìkẹ́ Rẹ̀?

Arákùnrin Kenneth Cook sọ ẹsẹ ìwé mímọ́ ọdún 2020, tó wà nínú Mátíù 28:​19, ó sọ pé: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn . . . , ẹ máa batisí wọn.” Ó jẹ́ ká rí bá a ṣe lè ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi.

Àwọn ìpàdé bí èyí máa ń fún wa níṣìírí nípa tẹ̀mí ká lè lo gbogbo okun wa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 2 Gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé ọdọọdún yìí máa wà lórí ìkànnì jw.org ní January 2020.