Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń ṣe ìpàdé látorí ẹ̀rọ ayélujára. Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe máa ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa nìyí

APRIL 3, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi Lọ́nà tó Yàtọ̀ sí Bí A Ti Máa Ń Ṣe É Tẹ́lẹ̀

Ọ̀pọ̀ Ìjọ Máa Ṣe É Látorí Ẹ̀rọ Ayélujára Nítorí Àrùn Corona tó Gbòde

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi Lọ́nà tó Yàtọ̀ sí Bí A Ti Máa Ń Ṣe É Tẹ́lẹ̀

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, títí kan àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a fi ń kọ́ni máa kóra jọ lọ́jọ́ Tuesday, April 7, 2020, láti ṣe ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù lọ́dún, ìyẹn Ìrántí Ikú Kristi. Àmọ́, ọ̀nà tá a máa gbà ṣe ìpàdé tọdún yìí á yàtọ̀ sí bá a ti máa ń ṣe é látẹ̀yìn wá nítorí àrùn Corona (COVID-19) tó gbòde kan. Nípa bẹ́ẹ̀, dípò kí wọ́n kóra jọ láwọn ibi ìjọsìn wa, ẹ̀rọ ayélujára làwọn èèyàn Jèhófà lọ́pọ̀ ibi láyé máa lò. Torí pé ẹ̀rọ yìí ní kámẹ́rà, á ṣeé ṣe fún wọn láti rójú ara wọn bí ẹni pé wọ́n wà pa pọ̀.

Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àrùn Corona yìí ti mú kí ìjọba ṣòfin pé àwọn èèyàn ò gbọ́dọ̀ kóra jọ níbikíbi. Torí náà, ọ̀pọ̀ ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ẹ̀rọ ayélujára téèyàn ti lè máa rójú àwọn tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀. Èyí mú kí wọ́n lè máa ṣe àwọn ìpàdé wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, òun náà sì ni wọ́n máa lo láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Kó lè rọrùn fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti gbádùn àsọyé tá a máa ń gbọ́ nígbà Ìrántí Ikú Kristi, a ti gbé àsọyé náà sorí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org.

Àwọn èèyàn tó lé ní ogún (20) mílíọ̀nù ló kóra jọ fún Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún tó kọjá. A nírètí pé ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa dara pọ̀ mọ́ wa láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí, yálà nípasẹ̀ ẹ̀rọ ayélujára tàbí lórí tẹlifóònù, wọ́n sì lè wo èyí tá a gbé sórí ìkànnì jw.org.

Láwọn ilẹ̀ kan, ṣe ni àrùn yìí túbọ̀ ń gbèèràn. Nítorí náà, àwọn ará wa ń fi àwọn ìkìlọ̀ àtàwọn ìránnilétí ìjọba sílò, wọ́n túbọ̀ ń wà lójúfò, wọ́n sì ń ṣọ́ra kí àrùn náà má bá ràn wọ́n. Bó ti wù kó rí, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa tì wá lẹ́yìn láti pa àṣẹ Jésù mọ́ tó sọ pé “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”​—Lúùkù 22:19.