OCTOBER 11, 2019
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW Ti Pé Ọdún Márùn-ún Báyìí
Láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn ni ẹgbẹ́ ará kárí ayé ti ń gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí lóṣooṣù lórí ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Bá a ṣe ń fojú sọ́nà fún àwọn ètò tí a ti là kalẹ̀ fún ọdún iṣẹ́ ìsìn 2020 àti àwọn ọdún tó tẹ̀ le e, ẹ jẹ́ ká wo àwọn àṣeyọrí tó kàmàmà tá a ti ṣe láti October 2014 tá a ti ń gbé ètò Tẹlifíṣọ̀n JW jáde.
A ti túmọ̀ ẹ̀ sí èdè ọgọ́sàn-án ó lé márùn-ún (185). Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀, èdè Gẹ̀ẹ́sì nìkan la fi ń gbé ètò jáde lóṣooṣù. Àmọ́ ní May 2015, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ ètò náà sí èdè tó lé ní ogójì (40). Ní báyìí, lẹ́yìn ọdún mẹ́rin péré, à ń gbé ètò yìí jáde ní èdè tó tó ọgọ́sàn-án ó lé márùn-ún (185).
Ètò tó kárí ayé ni. Torí pé gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé ni ètò Tẹlifíṣọ̀n JW wà fún, ọ̀pọ̀ fídíò tó jẹ́ ara ètò náà ni à ń ṣe ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kárí ayé. Lápá ìparí ètò oṣooṣù yìí, a sábà máa ń rí àwọn ìjọ tó wà ní àdádó lóríṣiríṣi ibi bí Ethiopia, Iceland, Mongolia, Saipan, Tuvalu àti Uganda. Orílẹ̀-èdè tó tó igba àti ọgbọ̀n (230) ni wọ́n ti ń wo ètò Tẹlifíṣọ̀n JW, títí kan àwọn ibi tó jẹ́ àdádó, bí erékùṣù Heard Island àti McDonald Islands tó jẹ́ àwọn erékùṣù tó tutù gan-an débi pé kò sáwọn tó fi ibẹ̀ ṣe ilé. Gbàrà tí ètò oṣooṣù kan bá jáde, iye igbà tí àwọn èèyàn wò ó tàbí tí wọ́n wà á jáde lóṣù tó jáde yẹn máa ń tó ìgbà mílíọ̀nù mẹ́jọ àtààbọ̀.
Àwọn ètò lóríṣiríṣi. Àwọn ohun tó ti wà lórí Tẹlifíṣọ̀n JW ti pọ̀ ju ohun tí a le fi ọgọ́ta (60) wákàtí wò lọ, lára wọn sì ni àsọyé, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, ìrírí, ìròyìn àti àwòkẹ́kọ̀ọ́. Láti ìgbà tá a ti gbé orin àkọ́kọ́ tó bá ètò oṣooṣù jáde, ìyẹn Ìgbésí Ayé Tó Dára Jùlọ, àwọn fídíò orin ti di ohun tó ń bá ètò oṣooṣù jáde déédéé. Èdè tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti méjìdínláàádọ́rin (368) là ń tú àwọn orin yìí sí báyìí.
Àwọn atọ́kùn ètò. Nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, àwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí nìkan ló ń ṣe atọ́kùn ètò lóṣooṣù. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí i lo àwọn olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tàbí káwọn nìkan jẹ́ atọ́kùn. Lápapọ̀, àwọn arákùnrin mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti ṣe atọ́kùn tàbí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ atọ́kùn fún ètò oṣooṣù náà.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìmọrírì. Arákùnrin kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ní àrùn rọpárọsẹ̀ tó sì ń fojú winá ìṣòro tí àrùn yìí fà, mọrírì àwọn orin tó máa ń bá ètò oṣooṣù náà jáde gan-an ni. Ó sọ pé: “Àwọn orin aládùn tó ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun yìí ti jẹ́ kí ń máa fojú tó tọ́ wo nǹkan, wọ́n sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti fara da ìṣòrò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé bá mi yìí. Ṣe ló máa ń yà mí lẹ́nu bí àwọn orin yìí ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa hùwà tó yẹ Kristẹni. Ẹ ṣeun gan-an fún àwọn orin yìí!”
Ìdílé kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí àrùn jẹjẹrẹ pa ọmọkùnrin wọn kékeré sọ bó ṣe rí lára wọn lẹ́yìn tí wọ́n wo ètò oṣooṣù ti November 2016. Wọ́n kọ̀wé pé:: “Ńṣe ni omijé ń dà lójú wa bí a ti ń wo fídíò orin Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán. Ó ṣe wá bí pé àwa ni àwọn òbí tó wà nínú párádísè nínú fídíò náà. Nígbà tó bá ṣe mi bí pé mi ò lè fara da ọgbẹ́ ọkàn náà mọ́, Jèhófà máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé òun mọ ìṣòro wa àti pé òun á ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á. Fídíò yẹn dà bí ìdáhùn Jèhófà sí àwọn àdúrà àtọkànwá tí a gbà.”
Tọkọtaya kan ní orílẹ̀-èdè Ukraine sọ ọ̀rọ̀ ìmọrírì yìí nípa ètò oṣooṣù náà: “Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW tí mu kí àwọn tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí di ara ìdílé wa!”
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ètò tó bọ́ sákòókò yìí, tó ń mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ wà níṣọ̀kan kárí ayé.—1 Pétérù 2:17.