NOVEMBER 20, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
Ìjì Líle Eta Ṣọṣẹ́ ní Central America, Cayman Islands, Bahamas, Jàmáíkà, Mẹ́síkò àti Amẹ́ríkà
Ibi tó ti ṣẹlẹ̀
Central America, Bahamas, Grand Cayman Island, Jàmáíkà, Mẹ́síkò àti apá gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
Ohun tó ṣẹlẹ̀
Ìjì líle Eta jà nílùú Puerto Cabezas tó wà lórílẹ̀-èdè Nikarágúà, ní November 3, 2020. Lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣọṣẹ́ láwọn apá ibòmíì ní Central America, ó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́
Ó dùn wá pé ọ̀gbàrá òjò gbé ọmọkùnrin kan lọ nílùú Tabasco lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lọmọ náà, ọmọ ọmọ tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sì ni
Nígbà tọ́wọ́ ìjì yẹn rọlẹ̀ díẹ̀, ó ṣọṣẹ́ ní Grand Cayman Island, Bahamas àti orílẹ̀-èdè Jàmáíkà. Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún ṣọṣẹ́ lápá ibi tí òkun ti ya wọ orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àtàwọn apá ibì kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe kan àwọn ará wa
Costa Rica
Àwọn akéde méjìdínláàádọ́fà (108) ló fi ilé wọn sílẹ̀
Àwọn akéde méje pàdánù gbogbo nǹkan ìní wọn
Guatemala
Àwọn akéde mẹ́tàlélọ́gọ́jọ (163) ní láti fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn márùndínláàádọ́rùn-ún (85) ti pa dà sílé
Ìdílé mẹ́ta pàdánù gbogbo nǹkan ìní wọn
Bákan náà, àwọn akéde mẹ́ta tó wà nínú ìdílé kan há sí àjà kejì ilé wọn kó tó di pé wọ́n wá gbà wọ́n sílẹ̀
Honduras
Àwọn akéde ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (1,984) ní láti fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ó kéré tán àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (376) ti pa dà sílé
Jàmáíkà
Àwọn akéde mẹ́rin ní láti fi ilé wọn sílẹ̀
Mẹ́síkò
Ní ìpínlẹ̀ Chiapas àti Tabasco, àwọn akéde ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti méjìdínlógún (1,618) ló fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn méjìléláàádọ́fà (112) ti pa dà sílé
Nikarágúà
Àwọn akéde ọgọ́rùn-ún méjì àti méjìdínlógójì (238) ló ní láti fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn ọgọ́rùn-ún méjì àti méjìlélọ́gbọ̀n (232) ti pa dà sílé
Panama
Àwọn akéde mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ló fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn mẹ́fà ti pa dà sílé
Amẹ́ríkà
Àwọn akéde méjìdínláàádọ́ta (48) ló fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ti pa dà sílé
Àwọn nǹkan tó bà jẹ́
Bahamas
Ilé kan bà jẹ́
Costa Rica
Ilé mẹ́ta bà jẹ́ kọjá àtúnṣe
Ilé mẹ́fà bà jẹ́
Guatemala
Ilẹ̀ tó ya ba ilé méjì jẹ́ kọjá àtúnṣe
Honduras
Gbọ̀ngàn Ìjọba méje bà jẹ́ díẹ̀
Nikarágúà
Ilé mẹ́tàléláàádọ́rin (73) bà jẹ́
Grand Cayman Island
Ilé mẹ́rin bà jẹ́
Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bà jẹ́ díẹ̀
Jàmáíkà
Ilé tó tó àádọ́ta (50) bà jẹ́
Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bà jẹ́
Amẹ́ríkà
Ilé tó tó mọ́kànlélógóje (141) bà jẹ́
Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́sàn-án (9) bà jẹ́ díẹ̀
Bá a ṣe ran àwọn ará wa lọ́wọ́
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America yan ìgbìmọ̀ mẹ́ta láti pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará wa, méjì lára wọn wà ní Mẹ́síkò, ọ̀kan tó kù sì wà ní Honduras. Láwọn orílẹ̀-èdè míì tí àjálù yìí ti ṣẹlẹ̀, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù tá a yàn nítorí àrùn Corona ló ń bójú tó ohun táwọn ará nílò
Ìjọ àtàwọn Ìgbìmọ̀ tá a yàn nígbà àrùn Corona ń pèsè ohun táwọn ará nílò láwọn ibi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń bójú tó
Àwọn alábòójútó àyíká ń fún àwọn ará níṣìírí látinú Bíbélì, ní pàtàkì àwọn ìdílé tó wà níbi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀
Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wà níbi tí àjálù náà ò dé ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó sá kúrò nílé, wọ́n ń gbà wọ́n sílé, wọ́n sì ń fún wọn lóúnjẹ
Àwọn ará wa rí i pé àwọn ń tẹ̀ lé òfin táwọn elétò ààbò ṣe lórí àrùn Corona bí wọ́n ṣe ń pèsè ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù náà bá
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìjì líle yìí bà jẹ́, inú wa dún gan-an bá a ṣe ń rí i táwọn ará wa ń ran ara wọn lọ́wọ́. Ó dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run wa á máa bá a lọ láti jẹ́ ‘ibi ààbò fún wa lákòókò wàhálà.’—Sáàmù 9:9.