Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Bí ọṣẹ́ tí Ìjì Líle Idai ṣe rí téèyàn bá wò ó látòkè ní ìlú Beira, lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì

MARCH 27, 2019
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ìjì Líle Tí Wọ́n Ń Pè ní Idai Jà ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Ilẹ̀ Áfíríkà

Ìjì Líle Tí Wọ́n Ń Pè ní Idai Jà ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Ilẹ̀ Áfíríkà

Ní Thursday March 14, 2019, Ìjì Líle Idai jà ní lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì, ó sì ṣọṣẹ́ títí dé orílẹ̀-èdè Màláwì àti Sìǹbábúwè. Ìjì yìí ló le jù nínú gbogbo ìjì tó tíì jà láwọn agbègbè yìí, ó balé jẹ́, ó bọ̀nà jẹ́, kódà ó lé ní èèyàn mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ tó fara gbá nínú àjálù yìí. Lọ́wọ́ báyìí, ìwádìí fi hàn pé àwọn tó bá ìjì náà lọ lé ní ọgọ́rùn-ún méjì (200). Ó dùn wá pé arábìnrin méjì àtàwọn ọmọ méjì tí ò tíì ṣèrìbọmi wà lára àwọn tó kú ní Mòsáńbíìkì, bákan náà, arákùnrin wa kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá náà kú ní Sìǹbábúwè nígbà àbàtà ya wọlé wọn, tó sì gbá a lọ.

Ìjì líle Idai ba Gbọ̀ngàn Ìjọba Inhamízua jẹ́ gan-an ní Mòsáńbíìkì

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Mòsáńbíìkì ròyìn pé ọ̀pọ̀ ilé àwọn ará àti Gbọ̀ngàn Ìjọba ni ìjì náà bà jẹ́, kódà ńṣe ló wó àwọn kan pátápátá. Ní Sìǹbábúwè, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa sọ pé ilé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) àwọn ará wa àti Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì ló bà jẹ́. Bákan náà, ní Màláwì, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ròyìn pé ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́rìnlélọ́gọ́ta (764) ilé àwọn ará wa ló bà jẹ́ pátápátá, ilé ọgọ́rùn-ún méjì ó lé kan (201) sì bà jẹ́ díẹ̀. Bákan náà, ó tún ba Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì jẹ́. A ti yan ìgbìmọ̀ mẹ́fà tó ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù láti pèsè ohun táwọn ará nílò, ìgbìmọ̀ méjì wà ní Mòsáńbíìkì, mẹ́rin sì wà ní Màláwì.

Ẹ̀ka igi ni wọ́n fi gbé òrùlé ilé àwọn arákùnrin méjì dúró ní Màláwì lẹ́yìn tí ògiri rẹ̀ wó lulẹ̀.

Àdánù tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí mú bá àwọn ará wa dùn wá gan-an. Àdúrà wa ni pé kí gbogbo àwọn ará tọ́rọ̀ náà kàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó lè fún wọn ní àlàáfíà tí wọ́n nílò.—Róòmù 15:13.