APRIL 16, 2021
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
Ìrántí Ikú Kristi Ọdún 2021—Fọ́tò Àwọn Ará Wa Kárí Ayé
Ní March 27, 2021, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé pàdé pọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi ká lè fi ìmọrírì hàn fún ohun tí Jèhófà àti Jésù Kristi ọmọ rẹ̀ ṣe. Ìgbà kejì rèé tí àjàkálẹ̀ àrùn náà ò jẹ́ káwọn ará lè pàdé pọ̀ lójúkojú láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi pa pọ̀. Síbẹ̀, a ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pa àṣẹ Jésù mọ́ tó sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
Nínú àwọn fọ́tò tó wà nísàlẹ̀ yìí, a máa rí bí àwọn ará wa ṣe múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2021 àti ìgbà tí wọ́n ń ṣe é.