APRIL 21, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ṣé Lọ́dún 2020—Ìkànnì JW.ORG
Iye Èèyàn Tó Lọ Sórí Ìkànnì Wa Ju Ti Ìgbàkigbà Rí Lọ
Bí àrùn COVID-19 ṣe ń tàn kárí ayé, làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà fi kún ìsapá wọn láti wàásù lásìkò Ìráńtí Ikú Kristi, àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ló ń lọ sórí ìkànnì jw.org kí wọ́n lè rí ìtúnù gbà látinú Ìwé Mímọ́, kí wọ́n sì tún ka ìròyìn nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí kárí ayé. Lóṣù March, iye àwọn tó lọ sórí ìkànnì wa pọ̀ fíìfíì ju ti oṣù February lọ, iye àwọn tó sì sọ pé àwọn máa fẹ́ ká kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ó Bíbélì pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ.
Iye àwọn tó ń lọ sí ìkànnì wa bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i nígbà tí àrùn náà bẹ̀rẹ̀. Lóṣù February, nǹkan bíi mílíọ́nù méjì àwọn èèyàn ló ń lọ sórí ìkànnì náà lójúmọ́, bó sì ṣe ń rí nìyẹn lọ́pọ̀ ìgbà. Nígbà tó di March, iye yẹn ti fò sí mílíọ́nù mẹ́ta lójumọ́, kódà ó máa ń ju mílíọ́nù mẹ́rin àtàabọ̀ lọ láwọn ọjọ́ tá a bá gbé ìròyìn nípa àrùn corona sórí rẹ̀. Ní ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi gangan, ìyẹn April 7, àwọn èèyàn tó ju mílíọ́nù méje ló lọ sórí ìkànnì wa, èyí tó sì pọ̀ jù nínú wọn ló lọ wo àkànṣe ìjọsìn òwúrọ̀ àti àsọyé Ìráńtí Ikú Kristi.
Arákùnrin Clive Martin tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka tó ń rí sí ètò ìṣiṣẹ́ MEPS ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófa ní ìlú Warwick ní ìpínlẹ̀ New York sọ pé: “Àsìkò yìí lọ́dún làwọn èèyàn máa ń lọ sórí ìkànnì jw.org láti wo ibi tí wọ́n ti lè ṣe Ìráńtí Ikú Kristi àti àkókò tó máa bọ́ sí. Ṣùgbọ́n lọ́dùn yìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó máa fẹ́ wá sí Ìrántí Ikú Kristi kò ní lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ, ìdí nìyẹn tá a fi gbé àkànṣe àsọyé àti Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2020 sórí jw.org ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún márùn (500) lọ. Ọ̀pọ̀ mílíọ́nù àwọn èèyàn ló wo àwọn àsọyé yìí látorí ìkànnì táwọn míì sì wà á jáde. Báwọn èèyàn tó pọ̀ ṣe lọ sórí ìkànnì jw.org lásìkò tí àrùn gbayé kan yìí jẹ́ ká rí i pé ipa kékeré kọ́ ní ìkànnì náà ń kó láti fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọ̀pọ̀ àwọn míì tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ní ìtùnú àti ìtọ́ni látinú Bíbélì.”
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sórí ìkànnì jw.org ló ń wá ohun tí wọ́n lè kà lórí bí wọ́n ṣe lè dènà àrùn kí wọ́n sì ní ìléra tó dáa, títí kan ìsọfúnni nípa béèyàn ṣe lè dènà àìbalẹ̀ ọkàn. A tún kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló tún ń lọ sórí ìkànnì náà láti wá ìsọfúnni látínú Bíbélì tó ṣàlàyé àwọn àmì ọjọ́ ìkẹ́yìn àti àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tí ìwé Ìfihàn orí Kẹfà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Ohun míì tó tún wọ̀ wá lọ́kàn ni iye àwọn èèyàn tó ń béèrè látorí ìkànnì pé ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì àtààbọ̀ (250) èèyàn la máa ń rí lójúmọ́ tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ lóṣù March iye yẹn lọ sókè sí nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àtààbọ̀ (350) lójúmọ́, tó túmọ̀ sí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá (11,000) èèyàn tó béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní oṣù yẹn. Láàárín ọjọ́ méjì péré, ìyẹn ọjọ́ Ìráńtí Ikú Kristi àti ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, àwọn èèyàn tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ ló béèrè látorí ìkànnì pé ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Jésù sọ pé àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run máa láyọ̀. (Mátíù 5:3) Inú wa dùn gan-an ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ìtùnú àti ìrànwọ́ wá sọ́dọ̀ Jèhófà àti ètò rẹ̀ lásìkò tí nǹkan ò rọgbọ yìí.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.