Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi: (apá òsì) Arákùnrin Anthony Morris ń sọ àsọyé tá a ṣàtagbà sí ìdílé Bẹ́tẹ́lì; (lókè lápá ọ̀tún) Arákùnrin Geoffrey Jackson àti (ìsàlẹ̀ lápá ọ̀tún) Arákùnrin Mark Sanderson ń sọ àsọyé látorí fídíò orí íńtánẹ́ẹ̀tì fáwọn ìjọ látinú iyàrá wọn.

APRIL 10, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ṣé Lọ́dún 2020​—Ní Bẹ́tẹ́lì Tó Wà Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ṣé Lọ́dún 2020​—Ní Bẹ́tẹ́lì Tó Wà Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Ní April 7, 2020, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ṣe Ìrántí Ikú Jésù Kristi, láìka bí àjàkálẹ̀ àrùn coronavirus ṣe gbòde kan sí. Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé: “Kò sí àrùn èyíkéyìí, bó ti wù kó tàn kálẹ̀ tó, tó lè mú ká má fi hàn pé a mọyì ohun ribiribi tí Jèhófà àti Jésù Kristi ṣe fún wa, bẹ́ẹ̀ sì ni, kò sì sóhun tó lè paná ìpinnu wa láti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi.” Ọ̀nà wo la gbà ṣe é lọ́dún yìí?

Èyí ni àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ tá a gbé jáde nínú ìròyìn wa tó ṣàlàyé nípa ọ̀nà táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kárí ayé gbà ṣe Ìrántí Ikú Kristi lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn coronavirus yìí. Nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Ká bàa lè tẹ̀ lé òfin tí ìjọba gbé kalẹ̀ pé káwọn èèyàn púpọ̀ má kóra jọ sójú kan, Ìgbìmọ̀ Olùdarí pinnu pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìrántí Ikú Kristi kan ṣoṣo ni wọ́n máa ṣètò fún gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Arákùnrin Anthony Morris ló sọ àsọyé náà nínú gbọ̀ngàn ńlá tó wà ní Warwick. Gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Amẹ́ríkà ló gbọ́ àsọyé náà nínú yàrá wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn díẹ̀ ló jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì mu wáìnì, àmọ́ wọ́n pèsè àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ fún gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì.

Àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó fáwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì kí wọ́n lè mú u lọ sílé

Àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì náà tún lè dara pọ̀ mọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìrántí Ikú Kristi tí ìjọ wọn ṣètò látorí ẹ̀rọ orí íńtánẹ́ẹ̀tì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà tó wà ní Bẹ́tẹ́lì láǹfààní láti sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi látorí fídíò orí íńtánẹ́ẹ̀tì.

Tọkọtaya kan tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Wallkill ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi nínú yàrá wọn

Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ló sọ pé, látìgbà táwọn ti ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi, tọdún yìí ló ṣàrà-ọ̀tọ̀ jù lọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wọn ní tààràtà, àmọ́ wọ́n mọ̀ pé àwọn wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn kárí ayé bí wọ́n ṣe ń rántí ìfẹ́ tó lágbára jù lọ tí Ọlọ́run wa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi ní sí wa.​—Jòhánù 3:16; Mátíù 20:28.