Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 13, 2019
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn 2019 Ni Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi Pọ̀ Jù Láti Ogún Ọdún Sẹ́yìn

Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn 2019 Ni Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi Pọ̀ Jù Láti Ogún Ọdún Sẹ́yìn

Inú wa dùn láti sọ fún yín pé lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2019, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) ló ṣèrìbọmi tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé láti ọdún 1999 tí iye àwọn tó ṣèrìbọmi máa ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta lọ. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run tó bù kún iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe tọkàntọkàn yìí!

Mánigbàgbé lọdún iṣẹ́ ìsìn 2019 jẹ́ torí a ṣe àwọn àpéjọ àgbáyé, a mú Bíbélì jáde lóríṣiríṣi èdè, àwọn ará sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn síra wọn bí wọ́n ṣe ń ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà àjálù. Díẹ̀ lára gbogbo àròpọ̀ ìròyìn ọdún iṣẹ́ ìsìn 2019 kárí ayé rèé. *

  • Iye Orílẹ̀-Èdè Tó Ròyìn: 240

  • Àwọn Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé: 20,919,041

  • Góńgó Akéde: 8,683,117

  • Àròpọ̀ Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 303,866

Àwọn ìrírí bí èyí máa ń wú wa lórí gan-an, ṣe ló máa ń jẹ́ kó túbọ̀ wù wá láti tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù Kristi pa fún wa nínú ẹsẹ ìwé mímọ́ ọdún 2020 tó sọ pé: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.”—Mátíù 28:19.

^ ìpínrọ̀ 3 Gbogbo àròpọ̀ Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdún 2019 Tàwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa tó wà lórí ìkànnì jw.org àti ètò ìṣiṣẹ́ JW Library.