OCTOBER 1, 2019
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
Ọgọ́rùn-ún Ọdún Rèé Tá A Ti Ń Tẹ Ìwé Ìròyìn Jí!
October 1, 2019 ló pé ọgọ́rùn-ún ọdún tá a ti ń tẹ ìwé ìròyìn Jí! Ọgọ́rùn-ún méjì àti ọgọ́rin mílíọ̀nù (280,000,000) ìwé ìròyìn yìí ni à ń tẹ̀ jáde lọ́dọọdún ní èdè ọgọ́rùn-ún méjì àti mọ́kànlá (211). Tá a bá ń sọ nípa ìwé ìròyìn tá à ń tú sí èdè tó pọ̀ jù lọ, tá a sì ń pín káàkiri jù lọ láyé, Jí! ló gba ipò kejì, Ilé Ìṣọ́ ni àkọ́kọ́.
Arákùnrin Samuel Herd, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé: “Jí! ti mú kó wu ọ̀pọ̀ èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí oríṣiríṣi àkòrí tó máa ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé bí ìwé ìròyìn náà ṣe rí àti bá a ṣe to ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ti yí pa dà láti àwọn ọdún yìí wa, síbẹ̀ irinṣẹ́ pàtàkì ló ṣì jẹ́ lára àwọn ohun tá a fi ń wàásù. Ohun ayọ̀ ló jẹ́ pé ó ti pé ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tá a ti ń tẹ̀ ẹ́ jáde, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń tì wá lẹ́yìn.”
Ní September 1919, ní àpéjọ mánigbàgbé kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní Cedar Point, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà la ti kọ́kọ́ sọ pé a ó máa tẹ ìwé ìròyìn The Golden Age jáde. Orúkọ tí ìwé ìròyìn Jí! ń jẹ́ nígbà yẹn nìyẹn. Nígbà tó di ọdún 1937, a yí orúkọ ìwé ìròyìn náà pa dà sí Consolation kó lè tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn èèyàn lọ́kàn pé a nílò ìtùnú. Níkẹyìn, lọ́dún 1946, a yí orúkọ ìwé ìròyìn náà pa dà sí Jí! ká lè fi tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn èèyàn pàfiyèsí ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé.
Inú wa dùn fún àṣeyọrí mánigbàgbé yìí bá a ṣe ń bá a nìṣó láti máa lo ìwé ìròyìn Jí! láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.”—Ìṣe 20:24.