Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 1, 2018
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àpéjọ Àgbègbè Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Ṣe Lọ́dọọdún Máa Bẹ̀rẹ̀ ní May 2018

Àpéjọ Àgbègbè Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Ṣe Lọ́dọọdún Máa Bẹ̀rẹ̀ ní May 2018

NEW YORK​—Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti múra tán láti bẹ̀rẹ̀ àpéjọ àgbègbè tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún ní Friday, May 18, 2018. Àkòrí àpéjọ àgbègbè tọdún yìí ni “Jẹ́ Onígboyà!” Kó tó dìgbà yẹn, kárí ayé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ké sí gbogbo èèyàn pé kí wọ́n wá síbi àpéjọ náà lọ́fẹ̀ẹ́. Ibi ọgọ́sàn-án (180) nílẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n á ti ṣe àpéjọ yìí.

Níbi àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, àwọn àsọyé, àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ àtẹ́tísí, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àtàwọn fídíò kéékèèké tí àpapọ̀ gbogbo ẹ̀ jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́ta (54) ló máa wà. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa wo fíìmù kan ní ọjọ́ tó gbẹ̀yìn àpéjọ àgbègbè náà, àkòrí ẹ̀ ni Ìtàn Jónà​—Ẹ̀kọ́ Nípa Ìgboyà àti Àánú. Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, àwọn fídíò orin tá a dìídì ṣe fún àpéjọ náà la máa fi bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àárọ̀ àti tọ̀sán.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Àwọn ìròyìn tá à ń gbọ́ lóde òní jẹ́ kó ṣe kedere pé tọmọdé tàgbà ló ń ṣàníyàn, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè kojú àwọn ìṣòro yìí. Gbogbo èèyàn la pè síbi àpéjọ àgbègbè tọdún yìí kí wọ́n lè wá jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn tó wúlò tó wà nínú Bíbélì.”

Déètì àti ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ kọ̀ọ̀kan wà lórí ìkànnì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn jw.org.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000