Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 16, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

2020 Iranti Iku Kristi​—Afirika

A Gbé Ètò Ìrántí Ikú Kristi Sórí Rédíò àti Tẹlifíṣọ̀n

2020 Iranti Iku Kristi​—Afirika

Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe lọ́dún 2020 yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tá a máa gbé ètò Ìrántí Ikú Kristi sórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n lónírúurú èdè, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi káàkiri Áfíríkà làwọn èèyàn sì ti gbádùn ètò náà.

Ohun tá a ṣe yìí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti méje (407,000) láti gbọ́ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi náà. Àìmọye àwọn míì tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló tún gbádùn ètò náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ iye àwọn èèyàn tó gbádùn ètò náà lápapọ̀, àmọ́ àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ibi tí ilé iṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣọ̀n ta àtagbà ètò náà sí kọjá mílíọ̀nù lọ́nà àádọ́jọ (150,000,000).

Nítorí àrùn Corona (COVID-19) tó gbòde, ẹ̀rọ ayélujára ni ọ̀pọ̀ àwọn ará wa kárí ayé lò kí wọ́n lè gbádùn àsọyé Ìrántí Ikú Kristi náà. Àmọ́ láwọn ilẹ̀ kan ní Áfíríkà, téèyàn bá máa gbádùn irú ètò bẹ́ẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹlifóònù, tàbí tó bá fẹ́ wà á jáde látorí ìkànnì, owó ńlá ló máa ná. Fún ìdí yìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé káwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì mélòó kan lọ sáwọn ilé iṣẹ́ rédíò àtàwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n tó wà lágbègbè wọn kí wọ́n sì jọ dúnàádúrà bóyá wọ́n á lè báwa gbé ètò náà sáfẹ́fẹ́ lówó tí kò ga ju ara lọ.

Kó tó di ọjọ́ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa mọ́kànlá ló ti kàn sáwọn ilé iṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣọ̀n tó wà lágbègbè wọn. Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ni Àǹgólà, Benin, Côte d’Ivoire, Democratic Republic of the Congo, Gánà, Kamẹrúùnù, Màláwì, Mòsáńbíìkì, Sáńbíà, Sẹ̀nẹ̀gà àti Sìǹbábúwè. Wọ́n sì ṣètò bí wọ́n ṣe máa gbé ètò Ìrántí Ikú Kristi náà sórí afẹ́fẹ́ láwọn ilé iṣẹ́ mẹ́rìndínlógójì (36) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlógún (16).

Àǹgólà

Ilé iṣẹ́ rédíò mẹ́fà ló gbà pé àwọn máa gbé àsọyé Ìrántí Ikú Kristi náà sáfẹ́fẹ́ ní èdè mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn èdè Ibinda, Kikongo, Kimbundu, Nyaneka, Portuguese àti Umbundu. Àwọn agbègbè táwọn èèyàn pọ̀ sí jù lórílẹ̀-èdè náà làwọn ilé iṣẹ́ rédíò náà ta àtagbà ètò náà sí.

Democratic Republic of the Congo

Ẹnì kan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣètò bó ṣe máa wo ètò náà lórí tẹlifíṣọ̀n torí pé àwọn ẹbí rẹ̀ ò nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ bó ṣe ń múra sílẹ̀ dìgbà tí ètò náà máa bẹ̀rẹ̀, bàbá rẹ̀ pè é látinú pálọ̀ pé, “Tètè máa bọ̀ o, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀!” Nígbà tó máa dé pálọ̀, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un pé ẹsẹ gbogbo ilé ti pé, wọ́n sì jọ gbádùn ètò náà látìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Àbẹ́ ò rí nǹkan, dípò òun nìkan, àwọn mẹ́wàá lọ́ jọ gbádùn ètò náà.

Ní abúlé kan tí kò jìnnà sílùú Luena, ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Àwọn pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì wa ò tiẹ̀ dá sí wa. Àmọ́, ẹ̀yin ò dẹ́kun àtimáa jọ́sìn Ọlọ́run yín láìka ti àrùn COVID-19 tó gbòde kan yìí. A máa dara pọ̀ mọ́ ìsìn yín!”

Gánà

Ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ gbà láti gbé àsọyé Ìrántí Ikú Kristi sáfẹ́fẹ́ lédè Twi. Kódà, ṣáájú ọjọ́ yẹn ni wọ́n ti ń polongo pé káwọn èèyàn rí i pé àwọn wo ètò náà. Kì í ṣe pé wọ́n polongo ẹ̀ nìkan, kódà wọ́n tún gbé àwọn fídíò wa kan sórí afẹ́fẹ́, ìyẹn fídíò Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú? àti Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?, títí kan àwọn fídíò orin wa, irú bí Ayé Tuntun àti Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán.

Sẹ̀nẹ̀gà

Arábìnrin kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ nípa Jèhófà Baba wa ọ̀run ni wọ́n ń sọ fàlàlà báyìí lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n! Ó yà mí lẹnu gan-an ni. Tí wọ́n bá gẹṣin nínú wa, wọn ò ní kọsẹ̀. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run wa!”

Arábìnrin míì sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ pé ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n máa gbé àsọyé Ìrántí Ikú Kristi sáfẹ́fẹ́, mo sọ nínú mi pé, ‘Àrùn COVID-19 kò jẹ́ ká lè pín ìwé ìkésíni náà bá a ṣe fẹ́. Àmọ́ ní báyìí tí ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ti gbà láti bá wa gbé e sáfẹ́fẹ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gbádùn ẹ̀.’ Kíá ni mo kàn sáwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mí, àwọn ìpadàbẹ̀wò mi, àwọn ẹbí mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, mo sì sọ fún wọn nípa ètò náà. Mẹ́sàn-án lára àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi àtàwọn ìdílé wọn ló gbádùn àsọyé náà. Ọ̀kan lára àwọn ìbátan mi tó ń gbé nílùú Ziguinchor pè mí lẹ́yìn tó gbádùn àsọyé náà, ó sì sọ fún mi pé òun á fẹ́ ká jọ sọ̀rọ̀ díẹ̀ sí i lórí àsọyé tóun gbọ́ náà. Ẹ wá wo bí inú mi ṣe dùn tó!”

Bí àwọn ilé iṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣọ̀n ṣe gbé ètò yìí sórí afẹ́fẹ́ mú kó túbọ̀ ṣe kedere pé “ohun gbogbo ṣeé ṣe fún [Jèhófà] Ọlọ́run.”​—Mátíù 19:26.