Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 17, 2021
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Tajiki Lórí Fídíò

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Tajiki Lórí Fídíò

Ní June 13, 2021, Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde Lédè Tajiki. A mú Bíbélì yìí jáde ní ẹ̀dà ti orí ẹ̀rọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí fídíò tá a gbà sílẹ̀.

Àwọn Ìsọfúnni Pàtàkì Nípa Iṣẹ́ Náà

  • Àwọn èèyàn tó tó mílíọ̀nù mẹ́rìnlá ló ń sọ èdè Tajiki, wọ́n sì fojú bù ú pé àwọn mílíọ̀nù márùn-ún lára wọn ló ń gbé ìlú Tajikistan

  • Nǹkan bí ọdún mẹ́rin làwọn atúmọ̀ èdè láti àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan fi ṣiṣẹ́ lórí ìtumọ̀ Bíbélì yìí

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní èdè Tajiki yìí máa jẹ́ káwọn tó ń kà á tètè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti bí wọ́n á ṣe fi í sílò. Kò sí àní-àní pé ó máa ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà, ẹni tó ṣe Bíbélì.”—Jémíìsì 4:8.