Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 3, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

A Mú Bíbélì Jáde Lédè Mẹ́fà Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní June 28, 2020

A Mú Bíbélì Jáde Lédè Mẹ́fà Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní June 28, 2020

Lákòókò tí àrùn corona ń jà ràn-ìn yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń mú Bíbélì jáde láwọn èdè tuntun. Ní June 28, 2020, a mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde láwọn èdè mẹ́rin yìí, ìyẹn èdè Swati, Tsonga, Zulu àti Chitonga. A tún mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jáde ní èdè Belize Kriol àti To-tonac. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará ò lè pàdé pọ̀ torí àrùn corona, inú wọn dùn gan-an bí wọ́n ṣe rí àwọn Bíbélì náà gbà látorí ẹ̀rọ. Àwọn àsọyé tí a ti gbà sílẹ̀ ni wọ́n fi mú àwọn Bíbélì náà jáde, orí Íńtánẹ́ẹ̀tì làwọn ará sì ti wò ó.

Swati, Tsonga àti Zulu

Arákùnrin Geoffrey Jackson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Swati, ó sì tún mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe jáde lédè Tsonga àti Zulu. Ẹ̀dà tó ṣeé kà lórí ẹ̀rọ làwọn ará rí gbà (wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀). Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì làwọn ará tó wà ní South Africa àti Eswatini ti wo ìpàdé pàtàkì yìí.

Bí àwọn Bíbélì tuntun lédè Swati, Tsonga àti Zulu ṣe rí rèé (láti apá òsì sí apá ọ̀tún)

Àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mọ́kàndínlógún ló ń sọ èdè Swati, Tsonga àti Zulu láwọn agbègbè tí ẹ̀ka ọ́fíìsì South Africa ń bójú tó, tó fi mọ́ àwọn akéde tó ju ẹgbẹ̀rún méjìdínlógójì (38,000) lọ.

Chitonga (Màláwì)

Arákùnrin Augustine Semo, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ló mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Chitonga ti Màláwì.

Ó lé ní ọdún méjì tí àwọn atúmọ̀ èdè fi túmọ̀ Bíbélì èdè Chitonga parí. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Ẹ̀ka èdè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà nínú èdè Chitonga, bí wọ́n ṣe n sọ èdè náà níbì kan yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́ níbòmíì. Torí náà, a rí i dájú pé ọ̀rọ̀ tó yé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ń sọ èdè náà la lò nínú ìtumọ̀ Bíbélì yìí. A tún ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣeé ṣe kó má fi bẹ́ẹ̀ yé wọn sísàlẹ̀ Bíbélì náà.”

Atúmọ̀ èdè míì sọ pé: “Kò ní ṣòro fáwọn akéde láti lo Bíbélì yìí lóde ẹ̀rí àti nípàdé, torí àwọn ọ̀rọ̀ tá a lò rọrùn, ó sì yéni. Torí náà, wọ́n á lóye ẹ̀ dáadáa tí wọ́n bá ń kà á.”

Belize Kriol

Arákùnrin Joshua Killgore tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Central America ló mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jáde lédè Belize Kriol. Àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ ló wo ìpàdé pàtàkì náà.

Nǹkan bí ọdún kan ààbọ̀ ni àwọn atúmọ̀ èdè mẹ́fà fi túmọ̀ Bíbélì náà parí. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ bí Bíbélì tuntun yìí ṣe wúlò tó, ó sọ pé: “Ní báyìí, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣẹ̀ṣẹ̀ ní Bíbélì tí ìtumọ̀ ẹ̀ péye, tó sì ṣeé gbára lé. Ṣe ni Bíbélì yìí dà bíi fìtílà tó ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ ṣe kedere sí wọn.”

Atúmọ̀ èdè míì sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àrùn corona ń jà ràn-ìn, àwọn ará tó ń sọ èdè Belize Kriol máa rí Bíbélì kà lédè wọn. Àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí máa tù wọ́n nínú gan-an, á fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, á sì jẹ́ kí wọ́n lè fara da ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí àtàwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.”

Àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin (867) ló wà ní ìjọ mọ́kàndínlógún (19) tó ń sọ èdè Belize Kriol ní ìlú Belize. Àwọn akéde méjìdínlọ́gọ́ta (58) ló ń sìn níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè Belize Kriol lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Totonac

Arákùnrin Jesse Pérez tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Central America ló mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jáde ní èdè Totonac. Àwọn tó tó ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì (2,200) tó wà ní ìjọ àádọ́ta (50) tó ń sọ èdè Totonac ló wo ètò náà.

Kò ju nǹkan bí ọdún mẹ́ta ó lé díẹ̀ táwọn atúmọ̀ èdè fi túmọ̀ Bíbélì náà parí. Bíbélì tuntun yìí máa wúlò gan-an, ó sì máa rọrùn fáwọn ará wa láti fi wàásù fáwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ (250,000) tó ń sọ èdè Totonac ní Mẹ́síkò.

Atúmọ̀ èdè kan sọ pé: “Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì yìí yàtọ̀ sí àwọn Bíbélì èdè Totonac míì, torí ọ̀rọ̀ tá à ń lò lójoojúmọ́ ni wọ́n fi túmọ̀ rẹ̀. Ní báyìí, ó máa rọrùn fún wa láti ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì fáwọn tó wà ládùúgbò wa.”

Atúmọ̀ èdè míì tún sọ pé: “Ó ti pẹ́ gan-an tó ti ń wu àwọn ará láti ní irú Bíbélì tó rọrùn kà yìí. Kó tó di pé wọ́n mú Bíbélì tuntun yìí jáde, Bíbélì tó wà lédè Sípáníìṣì làwọn ará wa máa ń lò tí wọ́n bá níṣẹ́ nípàdé àárín ọ̀sẹ̀. Ṣe ni wọ́n máa ń tú ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n fẹ́ lò sí èdè Totonac fúnra wọn. Ní báyìí tí àwọn ará ti ní Bíbélì tuntun yìí, wọn ò ní máa túmọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì fúnra wọn mọ́.”

Ohun tó jẹ́ kí ìtumọ̀ Bíbélì yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ ni pé, wọ́n ṣe àlàyé ìsàlẹ̀ sáwọn ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀ káwọn èèyàn lè rí oríṣiríṣi àwọn ọ̀nà míì téèyàn lè gbà sọ ọ̀rọ̀ náà. Ohun kan náà ni àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì náà àti àlàyé ìsàlẹ̀ náà túmọ̀ sí, àmọ́ wọ́n kọ ọ́ síbẹ̀ kí Bíbélì yìí lè yé gbogbo àwọn tó ń sọ èdè Totonac lóríṣiríṣi ọ̀nà.

Inú wa dùn gan-an pé àwọn ará wa rí àwọn Bíbélì yìí gbà lédè ìbílẹ̀ wọn. Ó dá wa lójú pé ìgbàgbọ́ wọn máa túbọ̀ lágbára bí wọ́n ṣe ń lo ‘idà ẹ̀mí’ yìí nígbà tí wọ́n bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ àti lóde ẹ̀rí.​—Hébérù 4:12.