DECEMBER 30, 2019
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
Lẹ́yìn Tí Ìjì Líle Tí Wọ́n Ń Pè Ní Idai Jà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pèsè Ìrànwọ́ fún Àwọn Tí Àjálù Bá
Ní March 2019, ìjì líle kan tí wọ́n ń pè ní Idai jà ní etíkun gúúsù ìlà oòrùn Áfíríkà. Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Malawi, Mozambique àti Zimbabwe yan ìgbìmọ̀ mẹ́rìnlá (14) tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù láti pèsè àwọn ohun táwọn ará nílò. Láwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ta yìí, àwọn ará ti ṣàtúnṣe sáwọn ilé kan, wọ́n sì tún àwọn míì kọ́. Ní báyìí, wọ́n ti ṣiṣẹ́ lórí ilé tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ààbọ̀ (650) lọ nínú ilé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,434) tí àjálù náà bà jẹ́. Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló bà jẹ́, wọ́n ti tún mẹ́jọ (8) kọ́, wọ́n sì ti ṣàtúnṣe sí mẹ́wàá (10).
Láàárín oṣù mẹ́sàn-án tó kọjá, àwọn ará tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ló ti yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará tí àjálù bá yìí. Ibi tó jìn lọ̀pọ̀ lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ti wá. Àwọn kan wá láti àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, àwọn míì sì wá láti Brazil, ilẹ̀ Faransé, Ítálì àti Amẹ́ríkà. Àwọn tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kọ́ àwọn ará tó jẹ́ ará ìlú níṣẹ́ bíríkìlà àti káfíńtà.
Nígbà tí ìjì líle náà jà ní ìpínlẹ̀ Manica àti Sofala lórílẹ̀-èdè Mozambique, ó ba nǹkan bí ìdá méje nínú mẹ́wàá jẹ́ lára àwọn nǹkan ọ̀gbìn àwọn ará wa. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ní kí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù pèsè oúnjẹ fáwọn ará, oúnjẹ náà á fẹ́rẹ̀ẹ́ kún ọkọ̀ akẹ́rù ńlá mẹ́wàá tí wọ́n fi ń kó sìmẹ́ǹtì. Àwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ ibẹ̀ ni wọ́n fi ráńṣẹ́, irú bí àgbàdo lílọ̀, ẹ̀wà, òróró, iyọ̀ àti ṣúgà. Wọ́n tún kó àwọn hóró àgbàdo, tòmátò àti ìrẹsì lọ fún wọn kí wọ́n lè gbìn ín.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Malawi ti ṣètò pé kí iṣẹ́ ìrànwọ́ yìí parí ní February 2020. Ẹ̀ka ọ́fíìsì Mozambique máa parí ní January 2020, nígbà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Zimbabwe ti parí iṣẹ́ ìrànwọ́ wọn lóṣù September 2019. Àpapọ̀ iye ti ètò ìrànwọ́ yìí máa ná wa jẹ́ nǹkan bíi bílíọ̀nù kan ààbọ̀ owó náírà (ìyẹn mílíọ̀nù mẹ́rin owó dọ́là).
Arákùnrin Trent Edson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Zimbabwe, tó sì tún wà lára Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ yìí sọ pé: “Ṣe ni inú àwọn ará tá a tún ilé wọn kọ́ ń dùn ṣìnkìn. Inú wa dùn gan-an bá a ṣe rí i táwọn ará yọ̀ǹda ara wọn tinútinú, títí kan àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Kódà, gbogbo wọn ló fẹ́ ṣe ohun tágbára wọn gbé.”
Àwa àtàwọn ará tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tí àjálù bá ní gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìfẹ́ táwọn ará fi hàn ní “ìgbà wàhálà” yìí.—Òwe 17:17.
Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìrànwọ́ tún ilé Arákùnrin Welosi Mbendera àti Arábìnrin Esinala Mbendera ìyàwó rẹ̀ kọ́, Ìjọ Nkolong’onjo ní orílẹ̀-èdè Malawi ni wọ́n wà
Arákùnrin Nehemiah Tigere àti Arábìnrin Fatima Sengami Tigere ìyàwó rẹ̀, dúró níwájú ilé tí wọ́n bá wọn tún kọ́ lórílẹ̀-èdè Zimbabwe
Alábòójútó àyíká ni Arákùnrin Witness Jabu àti Arákùnrin Augustine Kamadzi, àwọn méjèèjì ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ ìdílé kan tí àjálù náà ba ilé wọn jẹ́ nílùú Nchalo, lórílẹ̀-èdè Màláwì
Àwọn ará tó wà nílùú Chimoio ń já àgbàdo tí wọ́n máa pín fún àwọn ará lórílẹ̀-èdè Mozambique
Àwọn ará fẹ́ fi ọkọ̀ ojú omi sọdá Odò Shire kí wọ́n lè kó àwọn nǹkan ìrànwọ́ lọ fáwọn ará tó ń gbé nítòsí ààlà orílẹ̀-èdè Mozambique
Àwọn ará ń kó àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣe ìrànwọ́ láti orílẹ̀-èdè Malawi lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní abúlé Tengani lórílẹ̀-èdè Mozambique, ibẹ̀ ni wọ́n á ti pín in fún àwọn ará
Àwọn ará ń gba àwọn nǹkan ìrànwọ́ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní abúlé Tengani lórílẹ̀-èdè Mozambique