Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 4, 2019
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ohun Mánigbàgbé Tó Ṣẹlẹ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà​—A Ti Ń Tú Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa sí Ẹgbẹ̀rún Kan (1,000) Èdè Lórí Ìkànnì JW.ORG Báyìí

Ohun Mánigbàgbé Tó Ṣẹlẹ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà​—A Ti Ń Tú Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa sí Ẹgbẹ̀rún Kan (1,000) Èdè Lórí Ìkànnì JW.ORG Báyìí

Inú Ìgbìmọ̀ Olùdarí dùn láti sọ ohun mánigbàgbé tuntun tó ṣẹlẹ̀ bá a ti ń sapá láti sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. Ní báyìí, àwọn àpilẹ̀kọ, fídíò àti ohùn tá a gbà sílẹ̀ ti wà lórí ìkànnì JW.ORG ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) èdè, èdè adití tó tó ọgọ́rùn-ún kan (100) sì wà lára wọn.

August 2010, Arákùnrin Samuel Herd tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde ní Èdè Adití ti Ítálì (ó wà lórí ìkànnì jw.org)

Arákùnrin Gerrit Lösch, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí oríṣiríṣi èdè, àti nǹkan bí ọdún 1880 la ti bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, iye èdè tá à ń tú àwọn ìtẹ̀jáde wa sí ti yára pọ̀ sí i lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí.” Arákùnrin Geoffrey Jackson tóun náà jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, fi kún un pé: “Ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kí iye èdè tá à ń tú àwọn ìtẹ̀jáde wa sí tó dé ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́jọ (508). Àmọ́, ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ pé láàárín ọdún méje péré, iye èdè tá à ń tú ti fẹ́rẹ̀ẹ́ to ìlọ́po iye yìí, ìyẹn, láti ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́jọ (508) sí ẹgbẹ̀rún kan (1,000) èdè.”

Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nǹkan lèèyàn lè wà jáde látorí ìkànnì náà ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) èdè. Lára àwọn èdè yìí, ohun tó wà ní abala ìbẹ̀rẹ̀ àtàwọn abala míì lórí ìkànnì jw.org tí ṣe é kà ní èdè ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mọ́kànlélógún (821). Ìyẹn mú kó di ìkànnì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ láyé. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jíire ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ lára iṣẹ́ ìtumọ̀ náà ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́ta (350) kárí ayé.

Arákùnrin Izak Marais, tó ń bójú tó Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìtumọ̀ ni oríléeṣẹ́ wa ní Warwick, New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣàlàyé pé: “Àwọn ìpèníjà tá à ń kójú bá a ṣe ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a sì ń tẹ̀ wọ́n jáde ní ọ̀pọ̀ èdè kì í ṣe kékeré. Ìgbà míì wà tá a máa ń fẹ́ fi èdè tí ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ tẹ̀wé, àmọ́ tí kò ní sí lẹ́tà èyíkéyìí ní èdè náà rárá. Torí náà, fún ọ̀pọ̀ ọdún, a ti ṣe àìmọye lẹ́tà àtàwọn ọ̀nà tá à ń gbà kọ wọ́n, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti tẹ̀wé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. A tún ti borí ọ̀pọ̀ ìpèníjà, èyí tó jẹ́ ká lè ní onírúurú ìtẹ̀jáde lọ́pọ̀ èdè lórí ìkànnì jw.org. Kódà, ọ̀pọ̀ lára ẹgbẹ̀rún kan (1,000) èdè tá à ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí ló jẹ́ pé ẹ ò lè rí ìwé mìíràn lédè yẹn lórí ìkànnì míì.”

Arákùnrin Clive Martin, alábòójútó ẹ̀ka tó ń bójú tó ètò ìṣiṣẹ́ MEPS sọ pé: “Ọ̀kan lára ìpèníjà tá a dojú kọ ni bá a ṣe máa gbé àpilẹ̀kọ kan jáde lóríṣiríṣi èdè tí ìkọ̀wé àti lẹ́tà wọn yàtọ̀ síra, sórí ìkànnì kan ṣoṣo. Bí àpẹẹrẹ, mọ́kànlélógún (21) lára èdè tá à ń túmọ̀ sí ni wọ́n máa ń kọ láti apá ọ̀tún sí apá òsì. Ní ti ọgọ́rùn-ún kan (100) èdè adití tó wà lórí ìkànnì náà, ṣe la ní láti ṣe abala wọn lọ́nà tó máa mú kó rọrùn fún àwọn adití láti le lò ó.”

Àwọn ilé iṣẹ́ ńlá-ńlá sábà máa ń tú ìkànnì wọn sí kìkì àwọn èdè tó máa jẹ́ kí owó gọbọi wọlé fún wọn. Àmọ́ ní ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í ṣe tórí owó la ṣe ń tú àwọn ìtẹ̀jáde wa sí ọ̀pọ̀ èdè. Ohun tá a fẹ́ ni pé kí gbogbo àwọn tó ń wá láti gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́ ọ lọ́nà tó rọrùn ún lóye, tó sì fani mọ́ra.

Jèhófà ni ìyìn àti ògo yẹ fún bó ṣe ń bù kún ìsapá wa láti “sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Ó dá wa lójú pé títí dìgbà tí Jèhófà á fi sọ pé ó tó, á máa bá a nìṣó láti fún wa ni agbára àtàwọn ohun tá a nílò láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kárí ayé.​—Mátíù 28:​19, 20.