Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́​—Crimea

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́​—Crimea

Inúnibíni tó le gan-an táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń ṣe sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dé agbègbè Crimea báyìí. Ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti yọ orúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò lábẹ́ òfin, wọ́n sì tún fi hàn pé àwọn fẹ́ fòpin sí ìjọsìn wa pátápátá. Látìgbà tí ìjọba ti fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní April 2017, ńṣe làwọn agbófinró ń ya wọ ibi táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Wọ́n ti mú ọ̀pọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ti jù wa sẹ́wọ̀n. Ohun kan náà ni wọ́n ń ṣe fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Crimea báyìí.

November 15, 2018 ni ìgbà àkọ́kọ́ táwọn agbófinró ya wọ ilé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Crimea, ìlú Dzhankoy sì ni ìlú àkọ́kọ́ tí wọ́n lọ. Lọ́jọ́ yẹn, nǹkan bí igba (200) àwọn ọlọ́pàá àtàwọn sójà ló ya wọ ilé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n tú ilé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ nílùú Dzhankoy, níbi tí wọ́n máa ń kóra jọ sí láwọn àwùjọ kéékèèké láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó kéré tán, àwọn ọlọ́pàá márùndínlógójì (35) tó fi nǹkan bojú ló fipá wọ ilé Sergey Filatov, níbi táwa Ẹlẹ́rìí mẹ́fà kóra jọ sí. Ìwà ìkà tí wọ́n hù sáwa Ẹlẹ́rìí yìí mú kẹ́rù bà wọ́n gan-an. Àwọn ọlọ́pàá náà ní kí ọkùnrin ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin (78) kan kọjú sí ògiri, wọ́n tì í lulẹ̀, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lọ́wọ́, wọ́n sì lù ú nílùkulù débi pé wọ́n ní láti sáré gbé e lọ sílé ìwòsàn. Ẹ̀rù ba àwọn ọkùnrin àgbàlagbà méjì míì débi pé wọ́n gbé wọn lọ sílé ìwòsàn torí pé wọ́n ní ẹ̀jẹ̀ ríru tó lágbára gan-an. Ó bani nínú jẹ́ pé oyún bà jẹ́ lára obìnrin kan tí wọ́n ya bo ilé òun náà.

Lẹ́yìn tí wọ́n ya wọ ilé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà tán, wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Ọ̀gbẹ́ni Filatov lábẹ́ Apá Kejì Abala 282(1) nínú Ìwé Òfin Ìwà Ọ̀daràn ti Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, wọ́n sọ pé ó ń darí “ètò àwọn agbawèrèmẹ́sìn.” Ní March 5, 2020, ilé ẹjọ́ kan nílẹ̀ Crimea ní kí Ọ̀gbẹ́ni Filatov lọ lo ọdún mẹ́fà lẹ́wọ̀n. Bí wọ́n ṣe parí ẹjọ́ ẹ̀ tán ni wọ́n mú un lọ sẹ́wọ̀n.

Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé ọdún 2018 táwọn ọlọ́pàá tú ilé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Dzhankoy, àwọn ọlọ́pàá túbọ̀ ń fipá wọ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n bá fura sí pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Èyí tó ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn wáyé ní May 22, 2023. Láago mẹ́fà ààbọ̀ ìdájí, àwọn ọlọ́pàá tó lé ní mẹ́wàá já wọ ilé kan ní Feodosia, márùn-ún nínú wọn ló dira bí ẹni tó ń lọ sójú ogun. Wọ́n pàṣẹ fáwọn Ẹlẹ́rìí náà pé kí wọ́n dojú bolẹ̀, ohun tó lé ní wákàtí mẹ́ta sì ni wọ́n fi tú ilé wọn. Wọ́n wá mú ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí náà tó jẹ́ ọkùnrin lọ sí Sevastopol kí wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò.

Lẹ́yìn tí wọ́n tú ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n gbé wọn lọ sílé ẹjọ́. Méjìlá lára wọn ló wà lẹ́wọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, wọ́n sì ní kí wọ́n lo nǹkan bí ọdún mẹ́fà àtààbọ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan gbogbo wọn ni pé wọ́n ń bójú tó iṣẹ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn.

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

  1. April 17, 2024

    Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́sàn-án ló wà lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Crimea.

  2. May 22, 2023

    Àwọn ọlọ́pàá tú ilé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ní Feodosia. Wọ́n kó fóònù àti kọ̀ǹpútà wọn, wọ́n sì mú Ẹlẹ́rìí kan lọ.

  3. August 5, 2021

    Wọ́n tú ilé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ. Wọ́n fàṣẹ mú Aleksandr Dubovenko àti Aleksandr Litvinyuk.

  4. October 1, 2020

    Wọ́n tú ilé mẹ́sàn-án nílùú Sevastopol. Wọ́n fàṣẹ̀ mú Igor Shmidt, wọ́n sì fi sí àtìmọ́lé.

  5. June 4, 2019

    Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ya wọ ilé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́wàá nílùú Sevastopol. Lẹ́yìn náà, wọ́n fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Stashevskiy pé ó ń bójú tó iṣẹ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn.

  6. March 20, 2019

    Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ya wọ ilé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ nílùú Alupka àti Yalta. Wọ́n fọ̀rọ̀ wá Ọ̀gbẹ́ni Gerasimov lẹ́nu wò, lẹ́yìn náà wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó ń bójú tó iṣẹ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn.

  7. November 15, 2018

    Àwọn ọlọ́pàá tó ju ọgọ́rùn-ún méjì (200) àtàwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ya wọ ilé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ nílùú Dzhankoy, títí kan ilé Ọ̀gbẹ́ni Filatov.