Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 30, 2017
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Palẹ̀ Mọ́ fún Àwọn Ìpàdé Pàtàkì tí Wọ́n Fẹ́ Ṣe Lọ́dún 2017

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Palẹ̀ Mọ́ fún Àwọn Ìpàdé Pàtàkì tí Wọ́n Fẹ́ Ṣe Lọ́dún 2017

ÌLÚ NEW YORK—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ pe gbogbo èèyàn wá síbi àwọn ìpàdé pàtàkì tí wọ́n fẹ́ ṣe jálẹ̀ ọdún 2017.

Ní Tuesday, April 11, 2017, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé máa ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, tá a tún mọ̀ sí Ìrántí Ikú Kristi, èyí tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún, gbogbo èèyàn ni wọ́n sì pè. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù lọ́nà àkànṣe láti Saturday, March 18, 2017, kí wọ́n lè pe ọ̀pọ̀ èèyàn wá síbi ìpàdé náà bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ìwàásù àkànṣe náà á sì dópin ní April 11, 2017. Ìwé ìkésíni ni wọ́n fi ń pe àwọn èèyàn, ibi tí wọ́n ti máa ṣe ìpàdé náà lágbègbè wọn sì wà nínú ìwé náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló ṣe pàtàkì jù nínú ọdún.

Lẹ́yìn tí Ìrántí Ikú Kristi bá wáyé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa pe àwọn èèyàn wá gbọ́ àsọyé kan tó dá lórí Bíbélì fún ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú. Àkòrí rẹ̀ ni “Bí A Ṣe Lè Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Nínú Ayé Oníbìínú Yìí.” Ní ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri ayé, àkòrí àsọyé tí wọ́n máa gbọ́ ní ìpàdé wọn lópin ọ̀sẹ̀ tó bọ́ sí April 15 àti 16, 2017 nìyẹn.

Bẹ̀rẹ̀ láti May 19, 2017, àpéjọ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe lọ́dọọdún máa bẹ̀rẹ̀. Àkòrí àpéjọ náà ni “Má Sọ̀rètí Nù!” Ó máa bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì máa ṣe é wọ ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2018 lóríṣiríṣi ibi kárí ayé. Kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣe àpéjọ kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa kọ́kọ́ fi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta wàásù lọ́nà àkànṣe láti pe àwọn èèyàn wá síbi tí wọ́n á ti ṣe àpéjọ náà.

Ọ̀fẹ́ làwọn ìpàdé yìí, títí kan ìpàdé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. A rọ àwọn oníròyìn pé kí wọ́n kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè wọn tí wọ́n bá fẹ́ gbé ìròyìn ohun tó bá ṣẹlẹ̀ ní ìpàdé náà.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000