FEBRUARY 26, 2018
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
Ìjì Cyclone Gita Ṣọṣẹ́ ní Àwọn Erékùṣù South Pacific
Ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Cyclone Gita ṣọṣẹ́ gan-an lórílẹ̀-èdè Samoa àti American Samoa ní February 10 sí 11, 2018, kó tó wá jà lórílẹ̀-èdè Tonga ní February 12. Ìjì náà ò fi bẹ́ẹ̀ le nígbà tó bẹ̀rẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá, ọwọ́ ẹ̀ rinlẹ̀ gan-an. Ó mú kí omi yalé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, ó sì ba nǹkan jẹ́ gan-an.
Ìkankan nínú àwọn ará wa ò fara pa púpọ̀, ìkankan nínú wọn ò sì bá ìjì náà lọ. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ilé ló bà jẹ́ gan-an. Àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù fún àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí lóhun tí wọ́n nílò, bí oúnjẹ àti tapolíìnì.
Ní SAMOA, ilé mẹ́wàá ló bà jẹ́ gan-an.
Ní AMERICAN SAMOA, omi ya wọ ilé mẹ́ta. Àwọn ará lágbègbè náà ń fún àwọn tí ìjì ba ilé wọn jẹ́ ní ibi tí wọ́n lè gbé fúngbà díẹ̀.
Ó kéré tán, ilé mẹ́fà ló bà jẹ́ gan-an ní TONGA. Gbọ̀ngàn Ìjọba ni àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tí ilé wọn bà jẹ́ sùn mọ́jú.
Inú wa dùn pé ìkankan nínú àwọn ará wa ò fara pa púpọ̀, inú wa sì dùn pé àwọn tọ́rọ̀ kàn ti ń rí ìrànlọ́wọ́ tó yẹ gbà látọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwọn. Báwọn ará ṣe ń ran ara wọn lọ́wọ́ yìí jẹ́ ká rí irú ìfẹ́ tí Jésù sọ pé ó máa wà láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn òun.—Jòhánù 13:34, 35.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000
American Samoa: Panapa Lui, +1-684-770-0064
Samoa: Sio Taua, +685-20629
Tonga: Palu Kanongata’a, +676-25736