SEPTEMBER 24, 2018
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
Ohun Tí Ìjì Líle Mangkhut Dá Sílẹ̀
Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni ìjì líle tí wọ́n pè ní Mangkhut fi ṣọṣẹ́ ní ìwọ̀ oòrùn Òkun Pàsífíìkì àti Òkun South China. Ìròyìn yìí wá láti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó àwọn ará tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kàn lágbègbè náà.
Micronesia: Ní September 10, 2018, ìjì líle Mangkhut jà ní Rota, ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Northern Mariana. Ìjì yìí ló tíì le jù lára gbogbo ìjì tó ti jà ní Rota látọdún 2002. Inú wa dùn láti sọ fún yín pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó fara pa, kò sì sí nǹkan kan tó ṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ṣoṣo tó wà ní erékùṣù náà. A mú arákùnrin wa kan lọ sí ibòmíì fúngbà díẹ̀ kí wọ́n lè tún ilé ẹ̀ tó bà jẹ́ ṣe. Alábòójútó àyíká sì ti lọ sí erékùṣù náà kó lè fún àwọn ará ní ìṣírí.
Philippines: Ní September 15, 2018, ìjì líle Mangkhut (tí àwọn aráàlú máa ń pè ní “Ompong”) jà ní ìlú Baggao, lágbègbè Cagayan lórílẹ̀-èdè Philippines. Ìji Mangkhut ló tíì le jù lára gbogbo ìji tó jà ní Philippines lọ́dún yìí. Ńṣe ni iye àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ ń pọ̀ sí i, ní báyìí wọ́n ti tó mọ́kànlélọ́gọ́rin (81).
Ó dùn wá pé ìjì Mangkhut yìí fa sábàbí ikú arábìnrin wa kan tó ń gbé ní agbègbè Benguet, mẹ́rin lára àwọn ará wa sì fara pa. Ìròyìn tó kọ́kọ́ jáde fi hàn pé ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn àti méjìdínlógójì (938) ilé àwọn ará wa ló bà jẹ́, mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sì wó pátápátá. Ó kéré tán, Gbọ̀ngàn Ìjọba méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ló bà jẹ́, ọ̀kan sì wà lára wọn tó wó kanlẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ ya. A ti ṣètò àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù, ọ̀kan wà ní Baguio, ekejì ní Cauayan, ìkẹta ní Laoag, ìkẹrin sì wà ní Tuguegarao. Àwọn ló ń ṣètò ohun táwọn ará nílò láti gbé ẹ̀mí wọn ró, wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè máa jọ́sìn Ọlọ́run nìṣó. Láìpẹ́, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka máa wá sọ́dọ̀ àwọn ará níbẹ̀ kó lè fún wọn níṣìírí.
Hong Kong: Ìjì Mangkhut jà ní Hong Kong ní September 16, 2018. Ó ba nǹkan jẹ́ díẹ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ilé kan tí àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ń gbé. Ilé méjì tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí bà jẹ́ gan-an. Igi wó lu ọ̀kan, ìjì sì gbé òrùlé ìkejì lọ. Omi tún ba àwọn ilé mélòó kan jẹ́. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ti ń bójú tó àwọn nǹkan táwọn ará wa nílò ní Hong Kong.
Ọkàn wa wà lọ́dọ̀ àwọn ará wa tí ìjì líle Mangkhut yìí ṣọṣẹ́ lágbègbè wọn, a sì ń gbàdúrà fún wọn. Ó ń tù wá nínú bá a ṣe ń rí i pe àwọn ará wa ń fìfẹ́ ṣèrànwọ́ táwọn ará tọ́rọ̀ kàn nílò . Òótọ́ ni pé ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìdílé tẹ̀mí wa tó wà níṣọ̀kan yìí.—Òwe 17:17.