Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 27, 2018
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ilé Ẹjọ́ ní Slovakia Dá Martin Boor Láre Lẹ́yìn Àádọ́rùn-ún Ọdún Tí Wọ́n Ti Sọ Pé Ó Jẹ̀bi

Ilé Ẹjọ́ ní Slovakia Dá Martin Boor Láre Lẹ́yìn Àádọ́rùn-ún Ọdún Tí Wọ́n Ti Sọ Pé Ó Jẹ̀bi

Ní September 18, 2015, ilé ẹjọ́ kan nílẹ̀ Slovakia dá Martin Boor láre, ẹni tí wọ́n ti fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn tẹ́lẹ̀ torí pé ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun. Àádọ́rùn-ún (90) ọdún lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ dá Arákùnrin Boor lẹ́bi ni wọ́n pa dà wá dá a láre. Ẹjọ́ rẹ̀ ló tíì pẹ́ jù lọ lára àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ní Slovakia kí ilé ẹjọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá dá a láre.

Wọ́n Dá A Lẹ́bi Torí Pé Kò Yẹhùn

Fọ́tò Martin Boor rèé nígbà tí wọ́n mú un.

Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ni Martin lọ́dún 1920 nígbà tó dara pọ̀ mọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Orúkọ tí wọ́n mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn nìyẹn. Nígbà tó di October 1924, wọ́n ní kó wá wọṣẹ́ ológun. Àmọ́ ohun tó gbà gbọ́ ò jẹ́ kó gbà láti lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ológun tàbí kó jẹ́ ẹ̀jẹ́ àwọn ológun. Èyí mú káwọn aláṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé bóyá ó ní àrùn ọpọlọ, wọ́n sì ní kí dókítà wá yẹ̀ ẹ́ wò. Kò kúkú sóhun tó ṣe Arákùnrin Boor, ohun táwọn tó yẹ̀ ẹ́ wò sọ ni pé: “ohun tó gbà gbọ́ dá a lójú, kò lárùn ọpọlọ.”

Nígbà tó ti jẹ́ pé Martin ò ní àrùn ọpọlọ, ilé ẹjọ́ pinnu ní April 2, 1925 pé ìwà ọ̀daràn gbáà ló hù bó ṣe kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Kò pẹ́ tí Martin ṣègbéyàwó, àmọ́ ó fìgboyà fara mọ́ ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ dá fún un: wọ́n ní kó lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjì tí wọ́n á ti fìyà pá a lórí, bíi kí wọ́n ti òun nìkan mọ́lé, kí wọ́n má sì fún un lóúnjẹ dáadáa. Ṣùgbọ́n Martin ò lo ọdún rẹ̀ pé lẹ́wọ̀n. Nígbà tó di August 13, 1926, wọ́n dá a sílẹ̀ torí ìwà ọmọlúàbí tó ń hù nígbà tó wà lẹ́wọ̀n.

Ilé Ẹjọ́ ECHR Jẹ́ Kó Ṣeé Ṣe Láti Dá A Láre

Arákùnrin Boor kú ní January 7, 1985. Àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kọ́kọ́ kọ̀wé sílé ẹjọ́ ní 2004 pé kí wọ́n fagi lé ohun tí lé ẹjọ́ sọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ wọn ò gbà á wọlé. Lẹ́yìn ọdún méje, wọ́n ní kí Ilé Ẹjọ́ Bratislava I tún ẹjọ́ náà gbọ́ lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn ECHR) gbọ́ ẹjọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ẹjọ́ Bayatyan v. Armenia, tí wọ́n sì pàṣẹ pé ìwé àdéhùn European Convention on Human Rights fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé òun ò wọṣẹ́ ológun. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà lábẹ́ òfin láti yí ẹjọ́ tí wọ́n dá fún Martin pa dà, ọ̀rọ̀ náà ò lójú láwọn ilé ẹjọ́ tí wọ́n gbé e lọ nílẹ̀ náà. Àfìgbà tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ ẹnì kan tí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun kí wọ́n tó wá nǹkan ṣe sí ẹjọ́ Martin.

Ẹjọ́ Vajda: Àpẹẹrẹ Ńlá

Bíi Martin Boor, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Imrich Vajda, òun náà kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Nígbà ìjọba Kọ́múníìsì, wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n lọ́dún 1959 àti 1961. Nígbà tó di March 13, 2014, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ní Slovak Republic sọ pé kò jẹ̀bi, ní ìbámu pẹ̀lú òfin Czechoslovak Law No. 119/1990 Coll. tó dá lórí dídá ẹni tá a fẹ̀sùn kàn láre. Wọ́n dìídì ṣe òfin yẹn láti máa fi gbèjà àwọn tí wọ́n fìyà jẹ láìtọ́ nígbà ìjọba Kọ́múníìsì. Nínú ẹjọ́ Imrich Vajda, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba sọ èrò rẹ̀ fúngbà àkọ́kọ́ lórí bó ṣe di dandan kí ìjọba Slovakia tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR dá nínú ẹjọ́ Bayatyan, wọ́n ní ó ṣe pàtàkì kí wọ́n dá àwọn tí wọ́n ti sọ pé wọ́n jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀daràn tẹ́lẹ̀ láre torí pé ẹ̀rí ọkàn ni kò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe lórí ẹjọ́ Vajda jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ìdílé Martin Boor láti kọ̀wé ránṣẹ́ sí Ilé Ẹjọ́ Bratislava I pé kí wọ́n dá a láre ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Ilé ẹjọ́ fọwọ́ sí i, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní September 18, 2015. Òun ló fi jẹ́ pé àádọ́rùn-ún (90) ọdún lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ kọ́kọ́ dá Martin Boor lẹ́bi àti ọgbọ̀n (30) ọdún lẹ́yìn tó kú ni wọ́n dá a láre ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.

Ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR dá lórí ọ̀rọ̀ Bayatyan àti ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ṣe nínú ẹjọ́ Vajda ti jẹ́ kí wọ́n wá nǹkan ṣe sí ìwà ìrẹ́jẹ táwọn aláṣẹ ti hù tipẹ́. Ní báyìí, Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́kànléláàádọ́ta (51) ni wọ́n ti dá láre làwọn ilé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè Slovakia, bó tiẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ nínú wọn ló ṣẹ̀wọ̀n láàárín ọdún 1948 sí 1989.