Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 6, 2018
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Ké sí Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Láti Wá Síbi Ìràntí Ikú Kristi

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Ké sí Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Láti Wá Síbi Ìràntí Ikú Kristi

Ní March 3, 2018, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni fáwọn èèyàn kárí ayé láti wá síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, tá a tún mọ̀ sí Ìrántí Ikú Kristi. Tó bá di March 31, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní igba ó lé ogójì [240] orílẹ̀-èdè máa kóra jọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, torí wọ́n kà á sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ lọ́dún. Wọ́n tún ń fi ìwé ìkésíni náà pe gbogbo èèyàn wá síbi àkànṣe àsọyé kan tó dá lórí Bíbélì, tí àkòrí rẹ̀ sọ pé “Ta Ni Jésù Kristi Jẹ́ Gan-an?” Ó máa wáyé láàárín ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní March 19.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Lọ́dún 2017, àwọn tó lé ní ogún mílíọ̀nù ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi, nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìlá nínú wọn sì ni kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ka Ìrántí Ikú Kristi sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó yẹ kí wọ́n máa wà níbẹ̀ lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn àlejò kárí ayé náà fọwọ́ pàtàkì mú un. A fẹ́ kí gbogbo àwọn aládùúgbò wa rí ìwé ìkésíni gbà kí wọ́n lè pésẹ̀ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ní ibi tó rọrùn fún wọn.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000