MARCH 28, 2018
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé Fi Hàn Pé Àwọn Wà Níṣọ̀kan Nígbà Tí Wọ́n Ń Kọ Lẹ́tà Sáwọn Aláṣẹ ní Rọ́ṣíà
Ní Tuesday, March 21, 2017, Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún gbogbo àwọn ará kárí ayé pé kí wọ́n kọ lẹ́tà láti pàrọwà fún àwọn aláṣẹ tó wà nípò gíga, tí wọ́n ń halẹ̀ pé àwọn máa fòfin de iṣẹ́ wa jákèjádò orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. A ò mọ iye lẹ́tà tó dọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ní pàtó, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó kọ lẹ́tà yìí ló rí èsì gbà pa dà látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ pé àwọn rọ́wọ́ wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà kọ̀ láti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ táwọn èèyàn bẹ̀ wọ́n tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, tí wọ́n sì ṣi àṣẹ wọn lò láti gbógun ti àwọn ará wa lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn, lẹ́tà táwọn Ẹlẹ́rìí kọ jẹ́ kó ṣe kedere pé ìṣọ̀kan wà nínú ètò Jèhófà, èyí sì wúni lórí gan-an. Àwọn lẹ́tà yẹn tún jẹ́ káwọn ará wa ní Rọ́ṣíà mọ̀ pé gbogbo ẹgbẹ́ ará múra tán láti tì wọ́n lẹ́yìn.—1 Pétérù 2:17.
Kì í ṣe ohun kékeré ló ná ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti kọ lẹ́tà yìí ránṣẹ́. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, owó kékeré kọ́ ló máa náni láti fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí Rọ́ṣíà, torí náà, ṣe làwọn tó ní lọ́wọ́ fi owó wọn ṣètìlẹyìn fún àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ káwọn náà lè fi lẹ́tà ránṣẹ́. Ṣe làwọn akéde míì ní láti fi lẹ́tà wọn rán àwọn ọ̀rẹ́ wọn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì tí owó àtifi lẹ́tà ránṣẹ́ ò ti fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin ló kóra jọ ní ìdílé-ìdílé, ní ìjọ-ìjọ, kí wọ́n lè jọ kọ lẹ́tà náà, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ pa pọ̀. Èyí jẹ́ kí owó táwọn akéde máa ná láti fi lẹ́tà wọn ránṣẹ́ dín kù, ó tún jẹ́ kí wọ́n lè jọ ṣe nǹkan tẹ̀mí pa pọ̀, mánigbàgbé ló sì jẹ́ fún wọn.
Kódà, a gbọ́ pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gá iléeṣẹ́ kan tó ń fi nńkan ránṣẹ́ nílùú Barranquilla lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà sọ pé: “Ìṣọ̀kan tó wà láàárín yín kárí ayé yà mí lẹ́nu gan-an, ìkórajọ yín yìí nítumọ̀ ní pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ ti Rọ́ṣíà yìí. Mò ń fọkàn yàwòrán ẹ̀ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Barranquilla níbí ló ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìlú káàkiri ayé. Ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe yìí máa délé dóko, ì bá sì wù mí táwọn míì náà bá rí i bí ìdí tẹ́ ẹ fi ń ṣe ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe yìí ṣe ṣe pàtàkì tó.” Nílùú Anseong lórílẹ̀-èdè South Korea, òṣìṣẹ́ kan tó ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ ṣètò ibì kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kí wọ́n lè máa fi lẹ́tà wọn ránṣẹ́ látibẹ̀. Kódà, ó fún àwọn ará ní àpò ìwé tí wọ́n fi ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ síbikíbi ní àgbáyé lọ́fẹ̀ẹ́.
Yaroslav Sivulskiy, tó jẹ́ agbẹnusọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé pé: “Nígbà táwọn ará ní Rọ́ṣíà gbọ́ pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti sọ pé káwọn ará kọ lẹ́tà sáwọn aláṣẹ torí tiwọn, wọ́n gbà pé ibi yòówù kọ́rọ̀ náà já sí nílé ẹjọ́, àwọn onígbàgbọ́ bíi tàwọn wà lẹ́yìn àwọn.”
Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé: “Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ṣe ni lẹ́tà táwọn ará kọ yìí fi hàn pé ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà. Bí òpin ètò àwọn nǹkan yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, àfi ká wà níṣọ̀kan ká lè là á já. Bá a ṣe ń retí kí Jèhófà bá wa dá sí ọ̀rọ̀ tó ń lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́ la máa ṣe. Gbogbo wa ò sì ní yéé rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà. Ó dá wa lójú pé gbogbo ọ̀nà ni Ọlọ́run wa máa gbà bójú tó wọn.”—Sáàmù 65:2.
Austria
Bòlífíà
Bosnia àti Herzegovina
Denmark
Ecuador
Jámánì
Gánà
Guatemala
Indonéṣíà
Japan
Nepal
Ròmáníà
Rùwáńdà
Slovakia
Sípéènì
Siri Láńkà
Switzerland
Tàǹsáníà
Sáńbíà