Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 24, 2018
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Kenneth Cook Ti Di Ọ̀kan Lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Kenneth Cook Ti Di Ọ̀kan Lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Láàárọ̀ Wednesday, January 24, 2018, wọ́n ṣe ìfilọ̀ fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Kánádà pé arákùnrin Kenneth Cook ti di ọ̀kan lára àwọn Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé ni Arákùnrin Cook kó tó di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí.

September 1, 1982, ni Arákùnrin Cook di aṣáájú-ọ̀nà, October 12, 1984 ló sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Amẹ́ríkà. Àwọn arákùnrin mẹ́jọ tó jẹ́ ẹni àmì òróró ló para pọ̀ di Ìgbìmọ̀ Olùdarí báyìí.

Àdúrà gbogbo wa ni pé kí Jèhófà máa báa lọ láti bù kún Ìgbìmọ̀ Olùdarí bí wọ́n ṣe ń ṣe kòkáárí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé.​—1 Tẹsalóníkà 5:​12, 13

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000