Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 3, 2017
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ìjì Líle Hurricane Irma

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ìjì Líle Hurricane Irma

NEW YORK—Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Barbados, Dominican Republic, France, àti Amẹ́ríkà ti jẹ́ ká mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lẹ́yìn tí ìjì líle Hurricane Irma jà. Ohun tí wọ́n sọ fún wa rèé:

Àwọn àgbègbè ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Barbados tí ìjì yìí kọlù ni—Anguilla, Antigua and Barbuda, Montserrat, Saba, St. Eustatius, St. Kitts and Nevis, àti St. Maarten (apá ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Dutch). A gbọ́ pé ìjì yẹn ba nǹkan jẹ́ gan-an ní Barbuda àti St. Maarten.

Erékùṣù kékeré kan ni Barbuda, àwọn bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [1,800] ló gbé ibẹ̀. Kò sí iná, omi tàbí àwọn nǹkan amáyédẹrùn míì, kódà, ká sọ pé ilé márùn-ún péré nínú ilé ọgọ́rùn-ún kan tó wà níbẹ̀ ni kò bà jẹ́, ìdí nìyí tí ìjọba fi ṣètò àbójútó pàjáwìrì fún wọn níbẹ̀. Ìròyìn tá a gbọ́ ti jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n ti kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́kànlá tó wà níbẹ̀ lọ sí erékùṣù Antigua tó wà ní ìtòsí, níbẹ̀ ni Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ (DRC) ti ń bójú tó wọn. A ò gbọ́ pé ẹnikẹ́ni fara pa nínú wọn.

Àwọn akéde bí ọgọ́rùn-ún [700] méje ló ń gbé ní erékùṣù St. Martin (apá ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè French àti Dutch). Arábìnrin kan fara pa. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti rán àwọn kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Barbados àti France pẹ̀lú àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn lọ sí St. Martin láti lọ ran àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́.

Àwọn àgbègbè ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní France tí ìjì yìí kọlù ni—Guadeloupe, Martinique, St. Barthelemy, àti St. Martin (apá ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè French). A ò gbọ́ pé ẹnikẹ́ni kú tàbí ṣèṣe ní Guadeloupe àti Martinique.

Nǹkan bàjẹ́ gan-an ní erékùṣù St. Barthelemy (orúkọ tí wọ́n ń pe St. Barts lédè French), tó fi jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé ṣe láti kàn sí àwọn arákùnrin wa tó wà níbẹ̀. Àmọ́, alábòójútó àyíká kan ti sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì pé àwọn akéde ọgbọ̀n [30] tó wà níbẹ̀ wà ní àlááfíà, àti pé Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níbẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ bà jẹ́. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ti kó omi, oúnjẹ, àti àwọn nǹkan míì tí àwọn ará máa nílò láti erékùṣù Guadeloupe àti Martinique lọ fún àwọn ará wa ní erékùṣù St. Barthelemy àti St. Martin.

Gbọ̀ngàn Àpéjọ ní Guadeloupe. Wọ́n ń ṣètò àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ fi ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá.

Àgbègbè Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Dominican Republic. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti dá Ìgbìmọ̀ márùn-ún sílẹ̀ láti Ṣètò Ìrànwọ́ fún àwọn akéde ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn dín méjì [38,000] tó wà ní orílẹ̀-èdè yẹn. Ṣáájú kí ìjì líle Hurricane Irma tó jà, àwọn alábòójútó àyíká sọ fún àwọn alàgbà pé kí wọ́n lọ sí ilé àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin kí wọ́n lè rí i dájú pé wọn ti ṣe àwọn nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe. Wọ́n kó àwọn akéde ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́rin lé mẹ́ta [1,273] tó wà ní àwọn apá ibi tí wọ́n ti rí i pé ó ṣeé ṣe kí ìjì náà ti le gan-an lọ sí ibi tó rọlẹ̀ díẹ̀, wọ́n ní kí àwọn akéde ẹgbẹ̀rún méjì àti méjìdínláàádọ́rin [2,068] tí ilé wọn ò lè pèsè ààbò tó yẹ kó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn míì sì kọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ ìdílé míì tí ilé wọn lè pèsè ààbò.

Díẹ̀ nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ fara pa díẹ̀. Ilé àwọn ìdílé márùn-ún sì bàjẹ́. Ní àwọn ibì kan àwọn ìjọ tó wà ní àdúgbò ti ṣètò bí wọ́n ṣe máa tún wọn ṣe, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ [DRC] sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní àwọn ibòmíì. A ò gbọ́ pé ẹnikẹ́ni kú tàbí ṣèṣe.

Àwọn àgbègbè ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Amẹ́ríkà tí ìjì yìí kọlù ni—Bahamas, Florida, Georgia, Puerto Rico, Turks àti Caicos Islands, pẹ̀lú British and U.S. Virgin Islands. A ti jẹ́ kẹ́ ẹ gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé arákùnrin kan àti arábìnrin kan kú. A ò gbọ́ pé ará wa míì tún kú, àmọ́ ìròyìn tá a gbọ́ fi hàn pé àwọn arákùnrin mẹ́fà ló ti ṣèṣe àti pé àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta míì [3,000] ló ti sá kúrò nílé torí àjálù yẹn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin wa ní Florida àti Georgia ló ti gba àwọn míì sí ilé wọn.

Ní Florida, àwọn tó wà ní Ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè (RTO) ní Fort Lauderdale ti lọ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ West Palm Beach, ibẹ̀ ni wọ́n sì wà fún ọjọ́ mélòó kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ni kò fi sí omi, iná àti Íńtánẹ́ẹ̀tì ní Ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè yẹn. Gbogbo ẹ̀ ni wọ́n ti tún ṣe báyìí, gbogbo nǹkan sì ti pa dà sí bó ṣe rí tẹ́lẹ̀.

Wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kúrò níbi tí wọ́n ti ń ṣe ilé Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Àyíká Àtàwọn Ìyàwó Wọn àti Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run ní Palm Coast, Florida. Àwọn bí ogún [20] èèyàn ló ṣẹ́ kù sí ibẹ̀. Ilé náà kò bà jẹ́ púpọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò rí iná lò níbẹ̀.

Gbọ̀ngàn Àpéjọ Caguas, Puerto Rico. Wọ́n ń kó àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ fi ṣèrànwọ́ jọ.

Ẹ̀ka Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù lábẹ́ ìdarí Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti pèsè ìrànwọ́ tó yẹ fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa.

Wọ́n ti pèsè àwọn ibùdó káàkiri Amẹ́ríkà kó bàa lè ṣeé ṣe láti pín oúnjẹ àti omi fún àwọn tí àjálù náà dé bá. Yàtọ̀ síyẹn, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ [DRC] ní Puerto Rico ń ṣe ètò ìrànwọ́ fún àwọn ará wa tó wà ní erékùṣù yẹn.

Ní Caribbean, ó kéré tán ilé mọ́kànlélọ́gọ́ta [61] ló ti bà jẹ́ nígbà tí márùnléláàádọ́ta [55] míì fara pa díẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì ló ti bà jẹ́ gan-an.

Omi ń ya níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní ìlú Turks àti Caicos.

Àwọn arákùnrin láti orílé-iṣẹ́ àti ẹ̀ka ọ́fíìsì rìnrìn àjò lọ sí Florida àti àwọn erékùṣù tí àjálù náà dé láti lọ pèsè ìrànwọ́ fún àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa tó wà níbẹ̀. Iṣẹ́ ti ń lọ níbẹ̀.

Gbogbo ìgbà là ń gbàdúrà fún àwọn ará wa tó wà níbi tí ìjì líle Hurricane Irma ti ṣọṣẹ́, àti gbogbo àwọn tó ń pèsè ìrànwọ́ nípa tara, tó sì ń fi Bíbélì tu àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa nínú.—Róòmù 15:5; 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4, 7; 8:14.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Barbados: John Medford, +1-246-438-0655

Dominican Republic: Josué Féliz, +1-809-595-4007

France: Guy Canonici, +33-2-32-25-55-55