NOVEMBER 29, 2018
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
Àwọn Agbófinró ní Rọ́ṣíà Ya Wọ Ilé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mẹ́jọ Nílùú Crimea
Nírọ̀lẹ́ Thursday, November 15, 2018, nǹkan bí igba (200) agbófinró látọ̀dọ̀ Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà (ìyẹn FSB) ya wọ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ nílùú Crimea.
Torí bí àwọn agbófinró tó fi nǹkan bojú, tó sì dira ogun yìí ṣe ya wọ ilé àwọn ará wa, ó kó ìpayà bá àwọn kan, jìnnìjìnnì sì bò wọ́n débi pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ni ìfúnpá wọn ròkè gan-an, ó sì di dandan kí wọ́n gbé wọn lọ sílé ìwòsàn. Ó dùn wá gan-an láti sọ fún yín pé gìrìgìrì àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí tún jẹ́ kí oyún inú arábìnrin wa kan wálẹ̀.
Lọ́jọ́ yẹn náà, wọ́n ṣe arákùnrin kan tó ń jẹ́ Aleksandr Ursu ṣúkaṣùka. Ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin (78) ni, wọ́n fún un mọ́ ògiri, wọ́n tì í lulẹ̀, wọ́n sì kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọlọ́pàá tún da ìbéèrè bo àwọn Ẹlẹ́rìí míì.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Arákùnrin Sergey Filatov (tó wà lápá ọ̀tún) nìkan ni wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn. Àwọn aláṣẹ sọ pé ó jẹ̀bi ohun tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 282, Abala 2, apá 1, nínú Òfin Ìwà Ọ̀daràn ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà—tí Ìjọba Ilẹ̀ Rọ́ṣíà kàn nípá fún àwọn aláṣẹ ìlú Crimea pé wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé. Ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta (47) ni arákùnrin àkọ́kọ́ nílùú Crimea tí wọ́n máa fẹ̀sùn kàn lábẹ́ òfin pé ó jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn, ó sì ti bímọ mẹ́rin.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń kó àwọn ará wa lọ́kàn sókè tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn nípa báwọn agbófinró ṣe ń ya wọlé àwọn èèyàn, tí wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí wọn, a nígboyà pé Jèhófà, Ọlọ́run wa, máa fún wa lókun láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó kún fún àdánwò yìí.—Àìsáyà 41:10.